Binta Ayo Mogaji: Kìí ṣe iṣẹ́ tíátà làwọn òṣèré ti rí owó ra ọkọ̀ ńlá àti ilé àwòdamiẹnu

Binta Ayo Mogaji Image copyright Instagram/bintaayomogaji

Osere tiata to ba ni ọkọ gidi nile, to bimọ, to si ni ẹbi rere ko ni de idi sinima, ko maa ṣi ara silẹ tabi se afihan ihooho bi Ọlọrun se daa.

Ilumọọka osere tiata kan, Binta Ayọ Mogaji Odunẹyẹ lo woye ọrọ yii lasiko to n kopa lori eto ileesẹ tẹlifisan kan ni Naijiria.

Binta Mọgaji ni imura eeyan kan nigboro nii ohun se pẹlu idile to ti jade wa ati iwa ọmọluabi to ni, ti yoo si lee ronu jinlẹ pe iru oju wo ni aye fi n wo oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Binta, ẹni to sọ pe o ku diẹ ko pe ogoji ọdun ti oun ti n sere tiata, tun fikun pe oun korira ki obinrin maa si ara silẹ lasiko to ba n sere itage, lati igba ti oun si ti bẹrẹ ere tiata, aye ko ri ihooho oun ju ejika oun lọ.

Nigba to n dahun ibeere to nii se lori awọn obinrin onitiata to n si ara wọn silẹ lati polowo ọsẹ tabi ipara to n bo ara, Binta salaye pe, ti eeyan ko ba maa polowo sinima onihooho tabi asọ ti wọn fi n luwẹ, taa mọ si Bikini, ko si idi kankan fun obinrin lati si ara silẹ, fi polowo ọja kankan tabi fi fa oju awọn onibara rẹ mọra, nitori oju lasan ti to lati polowo ọsẹ tabi ipara.

Image copyright Instagram/bintaayomogaji

O ni iwa ara bibo to wọpọ laarin awọn osere tiata lọkunrin ati lobinrin lode iwoyi, ni ko ba oju mu, awokose saa ni awọn jẹ lawujọ, bẹẹ si ni ohun ti eeyan ba ni lọpọlọ lo ja ju, kii se afihan ọyan, idi abi ara bibo.

Binta ni ọpọ igba ti oun ba wa ni ẹnu isẹ, ni oun maa n tako abala ere to ba gba ka si ara silẹ tabi wa ni ihooho, bẹẹ ni ẹnu oun kii duro lati gba awọn ọjẹ wẹwẹ akẹẹgbẹ oun nimọran pe ki wọn dẹkun sisi ara silẹ, tori eyi ko bojumu fun ọmọluabi ati asa wa.

Lori awọn sinima to nii se pẹlu afihan ihooho ati iwa jagidi jagan abi lilo ibọn, Gbajugbaja osere tiata naa ni asa alasa ni a n kọ pẹlu sise fiimu onijagidijagan eyi to lodi si asa, ise ati ohun ajogunba wa lorilẹede Naijiria, idi si ree ti iwa ipanle se n pọ si lorilẹede yii.

Image copyright Instagram/bintaayomogaji

Binta Ayọ Mọgaji, lasiko to n fesi lori bi awọn osere tiata lode iwoyi se n ri owo nidi isẹ naa ju awọn osere tiata aye atijọ lọ ninu eyi ti Binta wa, osere tiata lobinrin naa ni, ohun ti onikaluku fi n jẹkọ, abẹ ewe lo wa.

"Awọn osere tiata tẹ ro pe wọn n ri owo pupọ lasiko yii ju asiko tiwa lọ, se inu isẹ tiata yii naa lẹ ro pe wọn ti n ri owo pupọ naa lati fi ra awọn ọkọ nlanla ati awọn ile awosifila tẹ ro pe wọn ni yii?

Image copyright Instagram/bintaayomogaji

Se ẹ ko ro pe 'ẹbun' kọ ni awọn ile ati ọkọ naa, ti kii si se inu isẹ tiata ti wọn n se ni owo ti wọn fi ra awọn ohun meremere yii ti wa?"

Binta wa rọ awọn akẹẹgbẹ rẹ lati maa se ere to mu ọgbọn lọwọ, ti yoo se agbelarugẹ asa ati ise wa, ti yoo si kọ awọn araalu lẹkọ gidi, nitori awokọse rere lo yẹ ki awọn onitiata jẹ lawujọ wa.