Oyo Isese Day: Aug 20 ni ọjọ́ àkànṣe àdúrà sí Ọlọ́run àtàwọn Alálẹ̀

Awọn to n bọ Sango

Yoruba ni tẹni ba dakẹ, tara rẹ maa n baa dakẹ ni.

Eyi lo mu ki awọn ẹlẹsin ibilẹ yika ipinlẹ Ọyọ fi n rawọ ẹbẹ si gomina Seyi Makinde lati ya Ogunjọ osu Kẹjọ ọdọọdun sọtọ gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu isẹ fun ayajọ ọdun awọn onisẹse.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn onisẹse naa, ti wọn korajọpọ si abẹ aburada ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Traditional Religious Worshippers Association Of Nigeria (TRAWASSO) parọwa naa lasiko ti wọn ls se ago laafin si Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji ni aafin rẹ lati fi sami ọdun Isẹse ti ọdun yii.

Image copyright Facebook/Seyi Makinde

Nigba to n sọrọ lorukọ awọn onisẹse naa, Akọda Awo tilẹ Ibadan, Oloye Ifalere Ọdẹgbọla ni o ti le ni ọdun meji ti awọn ti gbe ibeere naa siwaju ijọba to kogba wọle.

Amọ o ni gomina ana, Abiọla Ajimọbi ko fontẹ lu ibeere awọn, ti wọn si n rọ ijọba to wa lode nipinlẹ Ọyọ bayii, labẹ gomina Seyi Makinde lati dahun si ibeere naa, gẹgẹ bi akẹẹgbẹ rẹ ni ipinlẹ Ọsun ti se.

O ni o yẹ ka jẹ ki awọn araalu mọ pe Isẹse lagba, ayajọ Isẹse yii si ni wọn yoo lo lati gbakanse adura si Ọlọrun ati awọn Alalẹ, bẹẹ si ni Orunmila lo kọkọ fi ipilẹ ilana isẹse yii lelẹ saaju ẹsin Musulumi ati ti Kristiẹni, nitori gbogbo ẹlẹsin lo n tọpasẹ ara wọn de idi ẹsin isẹse.