BBNaija: Khafi la Mercy àti Cindi mọ́lẹ̀ nínú abala tó kẹ́yìn ìdíje ọ̀rọ̀ nípa Nàíjíríà

Khafilhat Kareem Image copyright Instagram/khafikareeem

Khafi Kareem to jẹ ọkan lara awọn to n kopa ninu eto agbelewo kan, Big Brother Nigeria, taa mọ si BBNaija ti gba ẹbun ọkọ ayọkẹlẹ lori eto naa.

Khafi to jẹ ọlọpaa nilẹ Gẹẹsi sọrọ loju opo Instagram rẹ pe, oun lẹni to ṣẹṣẹ ni ọkọ tuntun nigboro bayii.

Khafi jẹ ẹbun ọkọ ti ileeṣẹ to n ṣe mọto, Innoson Motors gbe kalẹ fun ẹni to ba gba ipo kinni, ninu idije sisọ ọrọ lori bi orilẹede Naijiria ṣe n wu wọn lori to.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Khafi ni wọn lo sọrọ iwuri nipa Naijiria julọ, lẹyin naa ni wọn kede rẹ gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idije naa.

Image copyright Instagram/acupofkhafi

Ni abala akọkọ, gbogbo oludije to wa nile lo sọrọ lọpọlọpọ nipa Naijiria, amọ Khafi, Mercy, Cindy ati Jackye nikan lo pegede de abala to kẹyin.

Mercy, Cindy ati Jackye ja fitafita lati moke ninu abala to kẹyin, ṣugbọn Khafi la gbogbo wọn mọ lẹ.

Ni ọsẹ to lọ niroyin sọ pe, ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi n ṣewadii fọnran kan lori ayelujara eyi ti ọpọ gbagbọ pe Khafi n ni ibalopọ pẹlu akẹgbẹ rẹ, Gedoni ninu rẹ.

Koda iroyin naa ni Khafi le padanu iṣẹ lori ọrọ naa nitori iwa ibanilorukọ jẹ lo jẹ ati pe ileeṣẹ ọlọpaa ko fun laye lati lọ kopa ninu idije BB Naija.