Seyi Makinde: Ìyá Akurẹ àti Iya Ibadan kìlọ̀ fún mi lóru ọ̀gànjọ́ làti sọ́ra fún olóṣèlú

Seyi Makinde Image copyright @seyiamakinde
Àkọlé àwòrán Awọn eniyan rere lee darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu

Ogbẹni Seyi Makinde, gomina ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe, bi oun ṣe jawe olubori ninu idibo to kọja jẹ ore-ọfẹ Ọlọrun.

Makinde salaye pe iya oun ko fẹ ki oun lọwọ ninu eto oṣelu orilẹ-ede Naijiria rara, nitori igbagbọ awọn eniyan pe awọn oloṣelu kii ṣẹni ire.

Gomina Makinde sọrọ yii nigba to n ṣe idupẹ agbole ni ijọ Aguda Dafidi Mimọ, ti o wa ni Ijọmu, ni ilu Akurẹ, ni ipinlẹ Ondo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni oun ko ni baba isalẹ ninu ẹgbe PDP ayafi Ọlọrun ọba. O sọ siwaju pe " Bi mo ṣe duro niwaju yin yii, mo jẹ ẹni ti o de ipo gomina lai ni baba isalẹ, afi Ọlọrun nikan ṣoṣo."

Nigbati mo fẹ bẹrẹ sii kopa ninu eto oṣelu, awọn iya mi mejeji, iya Akurẹ ati iya Ibadan pe mi loru ọganjọ, wọn si kilọ fun mi lede Akure ati ni ede Ibadan pe, ti awọn oloṣelu ba fun mi ni ohun kohun, mi o gbọdọ gbaa."

Wọn sọ eyi nitori igbagbọ wọn pe ẹni ire kan kii sẹgbẹ oṣelu.

Image copyright @seyiamakinde
Àkọlé àwòrán Mo jẹ ẹni ti o de ipo gomina lai ni baba isalẹ kankan, afi Ọlọrun Ọba

Sugbọn bi mo ṣe wa niwaju yin bayi, mo lee sọ kedere pe, ẹni ire lee darapọ mọ eto oṣelu.

Oluṣọ agutan ati oniwaasu nibi idupẹ naa, Simeon Borokini, wa rọ gomina Makinde lati mojuto ọrọ ọgbin, lọna lati gbogun airiṣẹ awọn ọdọ.