Seun Fakorede: Iṣẹ́ tí Seyi Makinde rán mi nipínlẹ̀ Oyo níkan ní màá jẹ́

SEun Fakorede ati Gomina Seyi Makinde Image copyright @seyiamakinde

Seun Fakorede ẹni ọdun mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tí gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn bíi Kọmísọna fún ìròyìn àtí eré ìdáráya ti ní, ẹní ran ni níṣẹ́ làá bẹ̀rù, à kìí bẹ̀rù ẹní tí àà jẹ fún.

Lásìkò tó ń dáhun ìbéèrè lórí ọ̀nà ti yóò gbà láti kóju àwọn agbààgbà nílé iṣẹ́ tí yóò maa darí pàápàá jùlọ àwọn àdari àti akọwe àgbà ilé iṣẹ́ náà tí òmíràn tilẹ̀ le bíi lọ́mọ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fakorede ní ọ̀rọ̀ náà dàbi ẹni ti wọ́n fi ọ̀pá àṣẹ ọba rán níṣẹ́ ni, ọ̀wọ̀ ọpá àṣẹ́ ọba ni wọ́n gbọdọ̀ máa fi wọ òun.

Image copyright @seyiamakinde

O fikun pe kìí ṣe gbogbo ẹní to ba kéré lọ́jọ́ orí náà ni ọpọlọ rẹ̀ kéré, nítorí náà, tọ̀wọ̀-tọ̀wọ̀ ní òun yóò máa fi ba gbogbo àwọn àgbààgbà ilé isẹ̀ náà ṣe.

Kọmisana tuntun naa ní orílẹ̀ èdè Nigeria jẹ́ ibi ti ìbọ̀wọ̀ fún ni ti ṣe pàtàkì, tí òun si ti ṣetan láti rii dájú pé òun ṣe ojúṣe oun botitọ́ àti botiyẹ, àti bibọwọ fun gbogbo ẹni tó ba tọ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀.

Seun fakorede ní pàtàkì júlọ, isẹ́ ti gomìnà Ṣeyi Makinde gbé lé òun lọ́wọ́ ló ṣe pàtàkì júlọ ti òun si ti ṣetan láti ṣee dé ojú àmìn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSeun Fakorede di kọmísánà ní ìpínlẹ̀ Oyo

O ni ti gbogbo àwọn àgbààgbà ilé iṣẹ́ ijọba ti wọn pin oun si bá ni ìfẹ́ ìpínlẹ̀ Oyo lọ́kàn, kò sí ẹni ti yóò ṣe ọ̀tẹ̀ bíkòṣe pe kí wọ́n fọ́wọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú oun fún àṣeyọri.