Sovereign Conference: Àwọn òǹwòye ní ìpàdé àpérò dára ṣùgbọ́n kò lè tàn ìṣòro Nàìjíríà

Ipade apero Naijiria to kọja lọ Image copyright Others

Aisi ẹmi ootọ lọdọ awọn olori wa lo mu ki Naijiria ma lee tẹle abajade awọn ipade apero taa ba ṣe bayii, tabi eleyi ta ti ṣe kọja.

Eyi ni ero awọn agbejọro kan ni Naijiria kan ti wọn fesi si ipe kan ti agba amofin, Afe Babalola pe, eyi to ni ki aarẹ Buhari pe ipade apero apapo, taa mọ si 'Constitutional Conference.'

Afe Babalọla ni asiko to lati wa wọrọkọ fi ṣada lori awọn ipenija to n koju Naijiria nitori ofin ọdun 1999 ta n lo mẹhẹ pupọ, to si daba pe ọna abayọ to wa nilẹ ni pipe ipade apero apapọ ilẹ wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lero ti agbẹjọro Kanmi Ajibola, ipe yii jẹ eyi to tọ ṣugbọn ko daju pe yoo jẹ ọna abayọ si awọn ipenija to n koju Naijiria lọwọ.

Ajibola, to tun jẹ Kọmisana fun ajọ to n mojuto ẹtọ ọmọniyan, Human Rights Commission ni, ko si ẹmi ootọ lara awọn olori Naijiria lati ṣe amulo awọn aba fun irufẹ ipade bẹẹ.

Image copyright others

''Ki a ṣe apero ju bẹẹ lọ, ko le dẹkun awọn aiṣedeede to wa ninu iwe ofin Naijiria. A ko ṣẹṣẹ ma ṣe apero, ko si le tan iṣoro wa bi awọn olori ko ba ṣetan lati ṣe amulo abajade wọn''

O ṣalaye pe ko boju mu bi awọn ẹya kan ti ṣe n da jẹ gbogbo mudunmudun ijọba awarawa, ti awọn to ku ko si ri anfaani ilu jẹ.

Ajibola ni awọn ikunsinu to n waye ko ṣẹyin pe pinpin ipo oselu laarin ẹkun kan si omiran, fi si apa kan ni Naijiria.

''Ipade apero gbọdọ ri pe wọn fi sinu iwe ofin Naijiria pe, ẹkun kọọkan to wa ni Naijiria (Geo political Zone) yoo ma ṣe ijọba lati igbadegba.

Bi oke ọya ba ṣe ijọba, ki wọn tun gba awọn ẹkun miran laaye lati se bẹẹ pẹlu tori ẹnikan kii jẹ, kilẹ o fẹ."

"Ko si igba ti wọn ba pe ipade apero ti ko ni la owo lọ"

Ọrọ Ajibola yii lo tun ṣe rẹgi pẹlu ti amofin James Ajibola to fi ilu Ibadan ṣe ibujoko.

Image copyright Facebook/James Stephen Ajibola
Àkọlé àwòrán Gbogbo awọn ipade apero ti a ti n ṣe bọ wa ko yatọ nipaṣe aba ti wọn n da

James Ajibola naa sọ pe, o ṣe pataki lati ṣe apero ṣugbọn ohun to jẹ ẹdun ọkan ni pe ''oṣelu ni awọn ijọba Naijiria n fi ipade apero ṣe.''

''Ko ba ṣe wa lanfaani ti ijọba ba ṣe amulo aba ti wọn da lẹyin ipade apero to waye lasiko ijọba aarẹ Goodluck Jonathan, nitori pe awọn olori pipe lo joko se apero naa''

Image copyright Getty Images

Ajibola ni iru iwa ki a maṣe tẹsiwaju pẹlu iṣẹ ti ijọba kan ba ṣe ku, lo n foju han lawọn ẹka ijọba lorisirisi ni Naijiria.

O ni ''Bi a ba ṣe iṣẹ ku, a ki fẹ pari rẹ nitori pe ijọba miran lo ṣe e. Bẹẹ naa la n ṣe nibi iṣẹ agbaṣe ti eleyi ko si jẹ ki idagbasoke ba Naijiria.''