Ekiti: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tó pa ìyàwò lárìnlọọ̀dù lẹ́yìn tó fipá bá a lòpọ̀

Wọn fi ẹwọn so ọwọ ọdaran kan sẹyin Image copyright daily post

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ arakunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan ti orukọ rẹ n jẹ Tunmiṣe Abraham ti wọn fi ẹsun kan pe o gbẹmi obinrin onile rẹ lẹyin to fi ipa ba a lo pọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti ni ọjọbọ to kọja ni iṣẹlẹ naa ṣẹ nilu Ado Ekiti.

Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti, ọgbẹni Asuquo Mba ṣalaye pe, inu ile ijọsin kan ni ilu Akurẹ lọwọ ti ba Tunmiṣe lẹyin to kan si awọn mọlẹbi rẹ.

Kọmiṣọna Ọlọpaa Asuquo Mba ni ilu Akurẹ ni Afurasi naa sa lọ lẹyin to ṣe iṣẹ laabi naa ti o si lọ fara sinko si inu ṣọọṣi kan.

O ni o pe awọn mọlẹbi rẹ pe, oun pa eeyan kan ni oun ko fi lee pada wa sile mọ o.

Ọga ọlọpaa ni ẹnu ẹgbọn rẹ obinrin ni wọn ti gba iroyin gbogbo ti wọn fi tọpinpin rẹ de ibi to wa, bakan naa lo si ni Tunmise ti jẹwọ pe lootọ ni oun ṣẹ ẹsẹ naa ati pe ibinu lo faa.

Image copyright Getty Images

Mba salaye siwaju pe Tunmise ni oun ko fipa ba oloogbe naa lopọ, arinyanjiyan lasan si lo ni o waye laarin oun ati arabinrin naa, to jẹ iyawo baba baba onile oun, Raphael Olanrewaju.

Tunmise salaye pe, iyawo larinlọọdu pe oun ni akalolo, alailẹkọ ati awọn orukọ miran ti ko ṣee gbọ seti ni oun ṣe paa.

O ni igi ti arabinrin yii fẹ la mọ oun lori ni oun gba lọwọ rẹ, ti oun si la a mọ leti.