Joint Security: Ọdẹ ìbílẹ̀, OPC, Aṣọ́gbó, ọlọ́pàá, ológun yóò máa pèsè ààbò nílẹ̀ Yorùbá

Nigerian Police

Ileesẹ ọlọọpa ipinlẹ Ogun ti fi idunnu rẹ han si idasilẹ ẹka eto aabo alajumose ni ilẹ Yoruba lati dẹkun ijinigbe ati ipaniyan.

Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi lo fi ọwọ idaniloju naa sọya nigba to n ba BBC Yoruba fọrọ jomi tooro ọrọ lori agbekalẹ ẹka aabo alajumọse nilẹ Kaarọ Oojire.

Bẹẹ ba gbagbe, iroyin kan ti tan kalẹ pe awọn gomina to wa lẹkun Guusu iwọ oorun Naijiria ti gba asẹ ni Abuja lati se agbekalẹ ẹka alaabo alajumọse ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ti yoo wa ninu igbimọ alaabo alajumọse naa ni awọn osisẹ ologun, ọlọpaa, aabo ara ẹni laabo ilu, asọgbo, ọdẹ ibilẹ, ọmọ ẹgbẹ Oodua (OPC) ati awọn osisẹ alaafia.

Oyeyẹmi salaye siwaju si pe eto aabo jẹ iṣẹ ajumọṣe fun tolori tẹlẹmu lawujọ wa, ki ifọkanbalẹ le wa kaakiri ilu.

O tẹsiwaju pe, awọn Ọlọọpa yoo ko ipa pataki lati ṣe atilẹyin fun idasilẹ ẹgbẹ alaabo tuntun naa ni ilẹ Yoruba, eyi ti yoo mu ki iwa ọdaran dinku lawujọ wa.

Ọga ọlọpaa naa ni, gbogbo eto lo ti to lati ọdọ ajọ naa fun iranlọwọ to nipọn fun ikogoja igbimọ alaabo alajumọse naa.

Bakan naa ni alukoro fun ẹka kan lara OPC ọgbẹni Ṣina Akinpelu ṣalaye wi pe lootọ ni OPC yoo kopa ninu eto naa.

O ni ipa ti o nipọn ni OPC yoo ko lori eto abo naa lati mu irọrun ba teru tọmọ.