Japan Visit: Ààrẹ Shinzo Abe kéde $413,000 owó ìrànwọ́ fún Nàìjíríà

Ijọba orilẹede Japan ti kede iranwọn iye owo to le ni ọkandinlaadọjọ miliọnu Naira, N149,919,000m( $413,000) fun orilẹede Naijiria ni Ọjọbọ ni ilu Yokohama.
Olootu ijọba ilẹ naa, Shinzo Abe kede iranwọ owo ọhun fun ẹka eto aabo ati ilera lorilẹede Naijiria nibi ipade to sẹ pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ni ilu Yokohama.
Eyi jẹ ọkan lara awọn anfaani to ti jẹyọ lati ibi apero TICAD7 lorilẹde Japan.
- A ń fikunlukun pẹ̀lú FBI láti mú àwọn "Yahoo Boys" tó kù- EFCC
- Amẹ́rika dá akẹ́kọ̀ọ́ padá nítori Facebook
- Ṣé àwọn ọmọ rẹ lè sọ Yorùbá tó àwọn ọmọ Amẹrika yìí?
- Wo orílẹ́èdè tí wọ́n tí ń dáwó ìsìnkú ara wọn pámọ́
Olootu ijọba Japan tun sọ pe orilẹ-ede Japan yoo ṣatilẹyin fun Naijiria ninu eto idibo aarẹ igbimọ gbogboogbo ajọ iṣọkan agbaye ẹlẹẹkẹrinlelaadọrin iru rẹ.
Bakan naa ni Ọgbẹni Abe beere iranwọ Naijiria ninu ero rẹ lati di ipo olori mu lagbaaye.
Ẹwẹ, Aarẹ Buhari lo anfaani apero TICAD7 niluu Yokohama lati bere iranwọ ilẹ Asia lati dẹkun awọn ole oju ni ọgbun Guinea atawọn to n pẹja lọna aitọ ninu ọgbun naa.
Bakan naa ni Aarẹ Buhari buwọlu iwe adehun €50m pẹlu ajọ EU lati ṣe iranwọ lori ọna ati ṣeto idagbasoke lapa ila oorun ariwa lorilẹede Naijiria.