Ọmọ́táyọ̀ Olútóyè: Àwọn ǹkan tó yẹ kí ẹ mọ̀ nípa Ọ̀jọ̀gbọ́n obìnrin àkọ́kọ́ nínú ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá lágbàyé

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Iṣẹ tokunrin n ṣe, obirin naa le ṣe e

Abi Ọjọgbọn Omọtayọ Olutoye ni ọjọ karundinlogun, oṣu kẹwa, ọdun 1935, ni ilu Eko, bi o tilẹ jẹ pe, ọmọ bibi ilu Ilogbo, ni ipinlẹ Ekiti ni.

O jẹ Ọjọgbọn obirin akọkọ ninu ẹkọ ede Yoruba ni orilẹ-ede Naijiria, ati ni gbogbo agbaye.

Oun naa tun ni obirin akọkọ ti yoo ṣíṣẹ ni ile ifowopamọ ni orilẹ-ede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionU.I Language Centre: Yorùbá ló làṣà àti èdè

Bakan naa ni o lọ si ile iwe Queens College, ni ilu Eko, laarin ọdun 1949 si 1953.

Lẹyin naa ni o tun lọ si St Agnes College, ti o wa ni Maryland, Ikeja, ilu Eko, laarin ọdun 1955 si 1956.

Ọjọgbọn yi tun tẹ siwaju lati kawe sii, ni University College, ilu Ibadan, laarin 1960 si 1961.

O kawe lawọn ile iwe miran ni Naijiria ati loke okun. Lara wọn ni, Fasiti ijọba apapọ ipinlẹ Eko, ni ọdun 1967 si 1970, ati University of Leeds, ni ilu ọba.

Awọn ibi ti o ti ṣiṣẹ

Ọjọgbọn Omọtayọ ṣiṣẹ olukọ laarin ọdun 1957 si ọdun 1963.

O tun ṣiṣẹ oniroyin nile igbohun safẹfẹ ti ijọba apapọ Naijiria, eyi ni Radio Nigeria, ni ọdun 1970 si ọdun 1971.

Bẹẹ lotun ṣiṣẹ ni Fasiti ijọba apapọ ilu Eko, gẹgẹ bi olukọ, ni ọdun 1971 si ọdun 1978.

Lẹyin naa lo kuro nibẹ lọ si ile iwe awọn oluko to wa ni Ikẹré Ekiti, lati tẹsiwaju ninu iṣẹ olukọ, ni ọdun 1979 si ọdun 1980.

Ọjọgbọn Omọtayọ tun gba igbega sii lẹnu iṣẹ ni Ikẹrẹ, nigbati o di adari fun ileewe naa laarin ọdun 1995 si 1997.

Lẹyin eyi ni o gba oye ọjọgbọn, ti o si jẹ olukọ agba, ni ẹka imọ ede Yoruba, lati ọdun 1983.

O jẹ ọkan lara awọn ti o lọ si ipade atunṣe iṣelu orilẹ-ede, eyi ti aarẹ orilẹ-ede yi tele ri, Olusegun Obasanjọ gbekale ni ọdun 2005.

Ọjọgbọn Omọtayọ fẹran aṣọ hihun, iwe kika, o jẹ iya to fẹran ọmọ, ati aya rere lọdẹ ọkọ rẹ, eyi ni, ajagunfẹhinti Olufemi Olutoye.