Ekiti: Àyọjúràn ni Fayoṣe tó yọjú sí Ilé Igbìmọ̀ Aṣòfin l'Ekiti

Peter Ayodele Fayose Image copyright @GovAyoFayose
Àkọlé àwòrán Fayoṣe yọjú sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin l'Ekiti lórí ọ̀rọ̀ owó Káńsù, óní kòséwu lòko

Ile Igbimọ Aṣofin ipinlẹ Ekiti ti sọ wi pe, "alejo apapandodo" ni Fayoṣe wa se lasiko ti o yọju sile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa.

Abẹnugan ile naa, Funminiyi Afuye lo sọrọ yi nigba to n fọrọjomitoro ọrọ pelu ile iṣẹ BBC.

Afuye wi pe, ile igbimọ asofin Ekiti ko tii fiwe pe gomina ana oun, sugbọn o kọ pinnu lati wa bẹ ile igbimọ aṣofin naa wo lai ro tẹlẹ ni.

Abẹnugan ile naa wa salaye siwaju pe, ile igbimọ aṣofin Ekiti ṣi maa kọwe si Fayose, lati wa farahan niwaju igbimọ to n risi ẹsun ti wọn fi kan an.

Fayoṣe yọjú sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin l'Ekiti lórí ọ̀rọ̀ owó Káńsù, óní kòséwu lòko

Peter Ayodele Fayoṣe, ẹni ti o jẹ gomina ana ni ipinlẹ Ekiti ti yọju si Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lori ẹsun ti wọn fi kan an nipa ọrọ owo Kansu.

Fayoṣe lo fi ọrọ yii lede lori opo Twitter rẹ nibi ti o ti sọ pe ko sewu loko, afi giri aparo.

O salaye pe "Mo ṣẹṣẹ kuro ni Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti ni, nibi ti moti ṣe ipade pelu agbẹnusọ ati awọn jankan jankan ile aṣofin naa.

Ọwọ mi mọ, mi o si bẹru ẹsun kankan bi o ti wu ki o ri."

Ile igbimọ asofin l'Ekiti ranṣe pe Fayose lori owo Kansu

Ṣe ẹ mọ Oṣokomọlẹ ipinlẹ Ekiti? hẹn ooo, gomina ana ni ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose naa ni.

Awọn ọmọ Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti ni fi aṣẹ ranṣẹ si gomina ana ni ipinlẹ naa pe afira, ko yara tete yọju ni o lati wa wi ti ẹnu rẹ lori bi awọn owo kan to jẹ ti ijọba ibilẹ ṣe rin kọlọkọlọ bi ọka to de inu ọka lasiko to wa lori oye.

Igbimọ to n ṣe konkaari aṣuwọn ilu ni ile aṣofin naa lo ranṣẹ pe Fayoṣe o.

Bakan naa ni wọn tun ni ki ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ awọn alaga kansu (ALGON) tẹlẹ, Ọgbẹni Dapọ Ọlagunju, kọmiṣọna tẹlẹ fun ọrọ ijọba ibilẹ, Ọgbẹni Kọla Kọlade pẹlu gbogbo awọn alaga kansu mẹrẹẹrindinlogun tẹlẹ ni ipinlẹ naa o yọju ni wara-n-ṣeṣa niwaju ile naa.

Ni oṣu kejila, ọdun 2018 lawọn aṣofin ipinlẹ Ekiti kọkọ gbegile awọn alaga kansu ọhun ki wọn to da mẹjọ ninu wọn pada ni oṣu keje, ọdun 2019.

Alaga igbimọ gbohun-gbaroye araalu ni ile aṣofin naa, Họnọrebu Adegoke Ọlajide ṣalaye pe lasiko ti awọn alaga kansu naa fi ara han niwaju ile ni wọn jẹwọ pe loṣooṣu lawọn maa n da owo ijọba ibilẹ wọn gba ọna miran, eyi ti wọn ni o wa ni ibamu pẹlu aṣẹ ti wọn ri gba latọdọ gomina ana ni ipinlẹ naa, Ayọ Fayoṣe.

Iye awọn ti yoo farahan niwaju ile naa ko mọ sibẹ o. Bakan naa ni wọn ni olori ile naa tẹlẹ, Pasitọ Kọla Oluwawọle pẹlu gbọdọ yọju o.