APC Kogi Primaries: Yahaya Bello la àwọn olùdíje mẹ́sàn án mọ́lẹ̀ fún àṣíá gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi

Yahaya Bello lẹyin ti wọn kede rẹ Image copyright others

Gomina Yahaya Bello lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Kogi tun gbe aṣia ẹgbẹ oṣelu naa le lọwọ.

Oun ni wọn fun lati fi dije ipo gomina lasiko idibo ti yoo waye loṣu kọkanla ọdun yii.

Ibo ẹgbẹrun mẹta ati ọdunrin o le mọkandinlaadọrin ni Yahaya fi bori awọn oludije mẹsan miran ti wọn jọ sa ere ije naa eyi to waye nilu Lọkọja.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán APC tun ti fa Yahaya Bello aklẹ lẹẹkansii

Gẹgẹ bii gomina Abubakar Badaru ti ipinlẹ Jigawa to ṣe alaga eto idibo naa ṣe sọ, Ọgbẹni Babatunde Irukera lo gbe ipo keji pẹlu ibo mọkandinlaadọfa ti Hassan Bewa si ṣe ipo kẹta pẹlu ibo mẹrinlelogoji.

Ibo mẹwaa pere ni Yahaya Audu ni ti Sanni Abdullahi ni tirẹ si ni meje.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Awọn eniyan Kogi a dibo gomina loṣu kọkanla ọdun

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2019 ni eto idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Kogi yoo waye.