Amole festival in Akure: Deji pàṣẹ kí gbogbo ọjà àti ṣọ́ọ̀bù wà ní títì pa

Igboro ilu Akure

Ọdun de, ka jọ maa ṣe amọdun laṣẹ Eledua ni adura awọn eniyan Akurẹ.

Gbogbo awọn ti o ba ti fi ọkan si ati lọ ra ọja loni ọjọ Ẹti nilu Akurẹ ko ni le e ṣe bẹẹ nitori Kabiyesi Deji ti ilu Akurẹ ti kede pe titipa ni ki gbogbo ọja ko wa.

Ko si idi meji gẹgẹ bi Ọba ilu Akurẹ ṣe sọ ju wi pe ni ọjọ Ẹti ni ayẹyẹ ọdun Amọle yoo waye nibẹ.

Gẹgẹ bii atẹjade kan ti akọwe iroyin fun igbimọ lọbalọba ilu Akurẹ, Adeyẹye Micheal fi sita, lọdọọdun ti ọdun yii ba ti fẹ waye lati igba iwasẹ wa ni wọn ti maa n ti ọja pa fun ọjọ kan ti ajọdun naa yoo fi waye.

Amọṣa wọn ni aaye wa fun igbokegbodo ọkọ ati awọn eeyan lasiko ti ọdun naa ba fi waye.

Wọn wa rọ gbogbo awọn olugbe ilu Akurẹ lati tẹle aṣẹ yii.

Bi a ko ba gbagbe, irufẹ ilana titi ọja gbogbo yii ko ṣajeji nitori idalu ni iṣelu.