Rape: Bàbà ọmọ ọdún márùndínlọ́gọ́rin kó HIV ran ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lẹ́yìn tó fi ipá báa lò

Ọwọ ọmọ kan ti wọn fi ipa mu mọlẹ

Baba ọmọ ọdun marundinlọgọrin kan ti ko kokoro arun HIV ran ọmọ ọdun mẹrinla kan lẹyin to fi ipa ba a lo ni ipinlẹ Rivers.

Iroyin ti a gbọ ṣalaye pe, baba agbalagba naa n gba itọju fun kokoro arun HIV ni ileewosan kan ni ipinlẹ Rivers.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọwọ ṣinkun ọlọpaa tẹ baba agbalagba naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Shadrack Ejinwo.

Ibanujẹ ibẹ ni pe iroyin naa ni lẹyin ọrọ pẹlu baba ọmọdebinrin wón jọ ṣe adehun lati maa san ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ati addọrin naira loṣooṣu titi di oṣu keji ọdun 2020.

Ohun ti a gbọ ni pe, ileewosan ti baba yii ti lọ n gba itọju fun kokoro arun HIV ni ọmọdebinrin yii ti n ṣiṣẹ olubanitaja bẹẹni awọn ọlọpaa ti fi baba agba yii silẹ lẹyin idunadura yii.

Gẹgẹ bii iwe adehun idunadura naa ṣe sọ, baba agbalagba, ọmọ ọdun marundinlọgọrin yii ni yoo maa ṣe kokari inawo fun itọju ọmọdebinrin ọhun titi di oṣu keji, ọdun 2020.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDomestic Violence: Ìjà láàrin lọkọlaya sọ aya dèrò ọ̀run