Kìí ṣe gbájúẹ̀ nìkan lọmọ Nàìjá ń ṣe lókè òkun, Yoruba ń mókè, wọ́n ń gbéṣẹ́ ńlá ṣe

Olutoye, Badenoch ati Ogunlesi Image copyright other
Àkọlé àwòrán Kìí ṣe gbájúẹ̀ nìkan lọmọ Nàìjá ń ṣe lókè òkun!

Kii ṣe olè, ọlẹ ati gbajuẹ nikan ni ọmọ Naijiria paapaa Yoruba n ṣe loke okun.

Ni ẹnu ọjọ mẹta yii, oniruuru iroyin iwa kotọ nipa awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria to wa loke okun lo n fọn kalekako lori ayelujara.

Koda, aarẹ Muhammadu Buhari funrarẹ ko ṣai mẹnu le ọrọ yii nibi ipade idagbasoke Afirika to lọ ṣe ni Japan.

Eyi lo wa n faa ti ọpọ fi n ṣe beere boya ohun rere kan tilẹ lee ti Nasarẹti yii jade.

Amọṣa diẹ niyi lara awọn ọmọ Yoruba to n da bi ẹdun, rọ bi owe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸtàn ni àwọn ọ̀rẹ́ fi ń tan èèyàn lọ si Libya pé iṣẹ́ gidi wà níbẹ̀

Dokita agba Oluyinka Olutoye:

Image copyright BBC Sport
Àkọlé àwòrán Bi a ba fi ọmọ we ọmọ...

Dokita agba Oluyinka Olutoye jẹ ọkan lara awọn ogo orilẹ-ede Naijiria ti itanṣan wọn n tan ka gbogbo agbaye fun ipa rere ti wọn n ko kaakiri.

Lati kekere ni Dokita Oluyinka Olutoye ti ni ifẹ si iṣẹ dokitaKíni ẹ mọ̀ nípa Ọmọ́táyọ̀ Olútóyè, Ọ̀jọ̀gbọ́n obìnrin àkọ́kọ́ nínú ẹkọ́ èdè Yorùbá lágbàyé

Gẹgẹ bii ọrọ rẹ, 'lati kekere ni mo ti maa n ṣe ere dokita kaakiri inu ile wa' nitori ifẹ rẹ si iṣẹ naa.

Koda aarẹ Muhammadu Buhari funrarẹ ko ṣai mẹnu le ọrọ yii nibi ipade idagbasoke Afirika to lọ ṣe ni Japan.A ń fikunlukun pẹ̀lú FBI láti mú àwọn "Yahoo Boys" tó kù- EFCC

Eyi lo wa n faa ti ọpọ fi n ṣebeere boya ohun rere kan tilẹ lee ti Nasarẹti yii jade?Ẹ yọjú sí FBI bí ẹ kìí bá ṣe ''yahoo boys'' - Abike Dabiri-Erewa.

Ki lo bi ero pe iwa buruku ni awọn ọmọ Naijiria n hu loke okun:

Ni ẹnu ọjọ mẹta yii, oniruuru iroyin iwa kotọ nipa awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria to wa loke okun lo n fọn kalekako lori ayelujara.

Amọṣa diẹ niyi lara awọn ọmọ Yoruba to n da bi ẹdun, rọ bi owe ni Olutoye Olayinka. Baba rẹ ni Alani ti ilu Ido-Ani, Oluwatomiloye I.

Ta ni Olutoye Olayinka?

Ọmọ ilu Idoani ni Dokita Olayinka Olutoye.

Awọn obi rẹ ni Ọgagun agba Olufẹmi Olutoye to ti fẹyinti ninu iṣẹ ologun ati Ọjọgbọn Ọmọtayọ Olutoye to jẹ Ọjọgbọn akọkọ ninu ẹkọ imọ Yoruba.

Awọn mẹfa ni awọn ẹgbọn ati aburo rẹ, mẹta jẹ obinrin, meji ninu wọn si jẹ ọkunrin.

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Lati kekere ni ọmọ ti yoo jẹ aṣamu ti maa...

Ileewe alakọbẹrẹ Lagos University Staff School ni o lọ ki o to kọri si ileewe girama King's College ni ilu Eko kan naa.

Lẹyin to pari ile ewe girama rẹ, Olutoye gba ọgba fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ lọ lati kọṣẹ imọ iṣegun oyinbo nibẹ.

Ọdun 1988 ni o kẹkọọ gboye ninu imọ iṣegun oyinbo ati iṣẹ abẹ.

Adebayo Ogunlesi: ọmọ ọjọgbọn onimọ iṣegun to ra papakọ ofurufu Gatwick lọwọ èèbó

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Ọdun 1988 ni o kẹkọọ gboye ninu imọ iṣegun oyinbo ati iṣẹ abẹ.

Tani ọlọpọlọ pipe oludokowo Adebayo Ogunlesi to gba aarẹ ile ifowopamọ agbaye ṣiṣẹ?

Ilu Makun ni ipinlẹ Ogun ni wọn ti bi Adebayo Ogunlesi ti o si ti wa di ilumọka agbẹjọro ati ouldukowo lagbaye

Pupo ninu awọn arinrinajo to ba gba papakọ ofurufu Gatwick kọja nilẹ Gẹẹsi a maa kan saara si bi wọn ti ṣe ṣe eto papakọ ofurufu naa.

Iyipada ti wọn mu ba papakọ naa waye lẹyin ti ile iṣẹ aladani kan raa lọwọ ajọ to n ṣamojuto rẹ BAA niye owo biliọnu pọun kan le diẹ lọdun 2009.

Ọrọ Gatwick kọ la fẹ fayọ ninu itan kekere yi bi kii ṣe ti ọmọ Yoruba to jẹ oludari ile iṣẹ Global Infrastructure Partners to ra Gatwick pa.

Ẹni ti a n sọrọ rẹ ni Adebayo Ogunlesi-ọmọ bibi ilu Makun nipinlẹ Ogun to si jẹ ilumọọka oludokowo lagbaye nii ṣe.

Ọmọ ti ẹya ba bi, ẹya nii jọ.

Lati kekere ni Adebayo ti ṣẹnu ṣamuṣamu ti a si le sọ wi pe ile lo ti baa.

Baba rẹ, ọjọgbọn Theophilus Ogunlesi ni onimọ iṣegun akọkọ to gba oye ọjọgbọn nilẹ Naijiria.

Ile iwe girama Kings College nilu Eko ni Adebayo lọ ti o si pegede nibẹ.

Lẹyin to pari ẹkọ, girama, o tẹsiwaju lọ ilẹ ẹkọ fasiti Oxford nibi to ti kawe gboye imọ nipa imọ iwa ẹda, oṣelu ati ọrọ aje, iyẹn Philosophy Politics and Economics.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'

Olukemi Olufunto Adegoke Badenoch

Image copyright kemi badenoch
Àkọlé àwòrán Ko si nkan ti ọkunrin n ṣe ti obinrin ko le ṣe

Ni oṣu, keje ọdun 2019 ni Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Bori Johnson yan arabinrin Olukemi Olufunto Adegoke Badenoch gẹgẹ bii minisita abẹle fun ọrọ awọn ọmọde ati idile.

Ni oṣu kinni, ọdun 1980 ni wọn bi i ni ilu Wimbledon lorilẹ-ede Gẹẹsi ṣugbọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ni awọn obi rẹ,

Dokita Fẹmi Adegoke ati Ọjọgbọn Feyi Adegoke ni orukọ wọn

Wọn gbe e pada wa si orilẹ-ede Naijiria lẹyin ibi rẹ, ṣugbọn o pada si ilẹ Gẹẹsi nigba ti o pe ọmọ ọdun mẹrindinlogun.

Ilu Eko lo ti lo igba ewe rẹ.

Ni ọdun 2017 ni wọn dibo yan an si ile igbimọ aṣofin ilẹ Gẹẹsi lati ṣoju fun ẹkun Saffron Walden.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLábẹ́ odò! Ìgbéyawó yìí lárinrin