Lẹ́yìn ìgbeyàwó ọdún mọ́kànlá, Saidi gbẹ̀mí Bọsẹ aya rẹ̀
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Domestic Violence: Ìjà láàrin lọkọlaya sọ aya dèrò ọ̀run

Ìja ojoojumọ laarin awọn mejeeji sú ara ilé, o sú ẹ̀bí àti iyekan paapaa.

Iroyin Kayeefi BBC Yoruba toṣu kẹjọ, ọdun yii da lori lọkọlaya Saidi ati Bọsẹ ti wọn n fojoojumọ ja ninu ile ni Akurẹ nipinlẹ Ondo.

Ifooya ati wahala ojoojumọ ni wọn fi jọ lo ọdun mọkanla ti wọn jọ gbe papọ ki ọlọjọ to de fun Bose.

Soji Ologunde, ẹgbọn Bose ni ko si ohun ti ẹbi n fẹ ju idajọ lọ lori Saidi nitori ko ṣẹṣẹ maa lu Bọsẹ ni alubami di ero ile iwosan ni ọpọ igba.

O ni ẹbi ti gbiyanju titi lati ya awọn mejeeji ṣugbọn Saidi a tun wa bẹ Bọsẹ pada ni.

BBC ba ara ile, ọrẹ, ojulumọ ati awọn agbofinro sọrọ lori iṣẹlẹ kayeefi yii to gba ẹmi odindin iyale ile.

Oga ọlọpaa Femi Joseph to wa nidii iwadii ẹjọ naa gba awọn obinrin nimọran lati sa asala fun ẹmi wọn.

Oga ọlọpaa naa ni ki awọn ọkunrin to n lu aya lọ wagbo dẹkun fun iru iwa yii, nitori o maa n la ẹmi lọ.