Lagos Police: Àwọ̀n ọlọ́kadà 123 láti Jigawa kìí se àwọn agbésùnmọ̀mì

Awọn ọlọkada lati Jigawa Image copyright Twitter/The Lagos State Govt
Àkọlé àwòrán Kini aduru gbogbo ero yii n bọ wa ṣe lEko lati ariwa ni ibeere awọn eniyan

Ile iṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ni awọn ti fi awọn ọlọkada to le ni ọgọfa to wa lati ipinlẹ Jigawa wa si ipinlẹ Eko silẹ nitori wọn kii ṣe ọdaran.

Agbẹnusọ ile-iṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Bala Elkanah ni awọn gbe igbeṣẹ naa leyin ti awọn ti ṣe iwadii iru eniyan ti wọn jẹ.

Elkanah fikun un wi pe lara awọn ọgọfa yii ti wa ni ipinlẹ Eko tẹlẹ. amọ ti wọn lọ si ile, ti wọn si padawa si Eko ni ibi ti wọn ti n ṣe iṣẹ ojo wọn.

Bakan naa lo ni ko si ewu kankan nitori ounjẹ ojo wọn ni awọn ti wọn mu naa wa wa si ipinlẹ Eko.

Àwọ̀n ọlọ́kadà 123 láti Jigawa kìí se àwọn agbésùnmọ̀mì-Ọlọ́pàá

Adari eto to n bojuto ayika ni ipinlẹ Eko, Yinka Egbeyemi ti ni awọn ọlọkada to le ni ọgọfa to wa lati ipinlẹ Jigawa wa si ipinlẹ Eko kii ṣe agbesunmọmi tabi ọdaran.

Egbeyemi lasiko to n ba BBC sọrọ ni pe iwadii awọn fihan wi pe irọ patapata ni iroyin to sọ pe awọn agbesunmọmi ti wọ ipinlẹ Eko.

Ninu ọrọ rẹ, O ni idi ti awọn fi fi oju wọn lede ni lati fi ọkan awọn eniyan balẹ wi pe ko si ewu loko longẹ, ati pe awọn ọlọkada to wa ni ọgọọrọ si ipinlẹ Eko, wa ṣiṣẹ ounjẹ ọjọ wọn.

Amọ, o fikun un wi pe ko ba ofin ipinlẹ Eko mu, ki ọgọọrọ eniyan wọ ipinlẹ Eko lati ṣiṣẹ wiwa ọkada lai ni iwe aṣẹ tabi papakọ ti wọn ti n ṣiṣẹ.

Adari eto to n bojuto ayika ni ipinlẹ Eko naa wa parọwa si awọn eniyan lati fi ọkan balẹ wi pe, ko si ẹwu fun awọn ara ipinlẹ Eko ati wi pe o ṣeeṣe ki wọn fi awọn ọlọkada yii silẹ laipẹ.

Àjọ tó ń mójútó àyíká l'Eko mú 123 ọlọ́kadà tó ń bọ̀ láti Jigawa

Ibeere nla ti awọn eniyan ipinlẹ Eko n beere ni pe kini gbogbo wọn fẹ wa ṣe ni Eko?

Ajọ to n ri si imọtoto ayika atawọn iwa ọdaran mii nipinlẹ Eko (Lagos State Environment Sanitation and Special Offenses Taskforce) ti mu awọn ọdọmọkunrin mẹtalelọgọfa ti wọn n bọ wa siluu Eko lati ipinlẹ Jigawa pẹlu alupupu wọn ti ọpọ mọ si okada lọjọ Ẹti.

Alaga ajọ LSESSOT, Yinka Egbeyemi ṣalaye pe ajọ naa mu awọn eeyan naa pẹlu ọkọ akẹru ti wọn wa ninu rẹ lagbegbe Agege lẹyin tawọn olugbe ilu Eko kan ta wọn lolobo pe ihuwasi awọn ọdọmọkunrin naa le ṣakoba fun eto aabo niluu Eko.

Ajọ naa gbe awọn ọkunrin naa lọ si olu ileeṣẹ wọn l'Oshodi fun ifọrọwanilẹnuwo lẹyin ti wọn mu ọkọ ti wa ninu rẹ.

Ọkan lara wọn, Shuaibu Haruna sọ pe iṣẹ l'oun wa wa silu Eko nitori oun ni iyawo ati ọmọ nile.

Haruna ni agbegbe Isolo l'oun fẹ gbe, ati pe oun ti san ẹgbẹrun meje naira fun owo ile fun ibi t'oun fẹ de si nibẹ.

Ẹlomiran ninu awọn ti wọn mu, Mohammed Ibrahim ni tiẹ sọ pe oun wa silu Eko lati ṣiṣẹ lẹyin t'oun ti ṣiṣẹ oko dida tan.

Ibrahim ni ilu Badagry l'oun ti n lọ ba ẹgbọn to ti n gbe nibẹ tẹlẹ.

Image copyright Twitter/The Lagos State Govt
Àkọlé àwòrán Ibrahim ni ilu Badagry l'oun ti n lọ ba ẹgbọn to ti n gbe nibẹ tẹlẹ.

Ọgbẹni Egbeyemi fikun ọrọ rẹ pe awọn mejidinlaadọta ninu wọn ṣalaye pe awọn gbe okada wa lati fi ṣiṣẹ l'Eko nigba tawọn to ku ni awọn wa ṣiṣẹ niluu Eko lati rowo ni.

Alaga ajọ LSESSOT ṣalaye siwaju si i pe awọn o ba ohun to le ṣakoba fun ẹnikẹni lara wọn ṣugbọn o ni iwadii si n tẹsiwaju lori awọn naa.