Daddy Freeze: 'Kátàkárà ni owó orí gbígbà lórí ọmọbìnrin jẹ́'

Daddy Freeze Image copyright Instagram/daddyfreeze

Sisọ omo soko ẹru ni gbigba owo ori ìdána nibi igbeyawo -Daddy Freeze

Yoruba bọ, wọn ni dandan lowo ori, tulasi laṣọ ibora. Ṣugbọn Gbajugbaja atọkun eto ori redio, Ifedayo Olarinde ti ọpọ mọ si Daddy Freeze sọ pe owo ẹru ni owo ori sisan lori obinrin tumọ si.

Daddy Freeze sẹleri pe oun ko ni gba owo ori lori awọn ọmọbinrin ti Eleduwa fi ta oun lọrẹ to ba to asiko fun wọn lati ṣe igbeyawo.

O ni owo ori sisan da bi keeyan maa ta tabi ra ọmọbinrin to n lọ sile ọkọ, nitori naa o yẹ kawọn obi dẹkun ori gbigba.

Daddy Freeze to fọrọ yii lede loju opo Instagram rẹ. O ni lootọ ni owo ori sisan wa ninu Bibeli, amọ, ko wa ni ibamu pẹlu ilana ẹsin awọn ọmọlẹyin Kristẹni.

Ọgbẹni Olarinde ṣalaye pe kii ṣe gbogbo nnkan to wa ninu Bibeli lo ba ilana ẹsin Kristẹnu mu.

O fikun ọrọ rẹ pe Bibeli ko sọ nibi kankan pe o di dandan fun ẹnikẹni lati san owo ori niwọn igba to jẹ pe gbogbo awọn onigbagbọ ti di ọkan ṣoṣo ninu Kristi.

O fidi ọrọ rẹ mu lẹ ninu iwe Galatia ori kẹta ati ẹsẹ kejinlọgbọn.

Daddy Freeze ni iṣẹlẹ buruku kan to dabi owo ori sisan ninu Bibeli ni eyi ti Dafidi fi pa igba eeyan to si tun ge nnkan ọmọkunrin wọn nitori o fẹ fi ọmọbinrin Ọba Sọọlu ṣe aya.