Herbal Medicine: Gbígboyè fásítì nínú iṣẹ́ ìṣègùn ìbílẹ̀ dára, àrídájú gbọdọ̀ wà lórí rẹ̀

Oniṣegun ibilẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Herbal Medicine: Gbígboyè fásítì nínú iṣẹ́ ìṣègùn ìbílẹ̀ dára, àrídájú gbọdọ̀ wà lórí rẹ̀

Kikọ sii nipa iṣegun ibilẹ yoo mu idagbasoke ba eto ilera -Ọjọgbọn Faduyile (NMA)

Ẹgbẹ awọn oniṣegun oyinbo ni Naijiria, (Nigeria Medical Association) ohun to dara ni tawọn ileewe giga fasiti lorilẹ-ede Naijiria ba bẹrẹ si ni fawọn akẹkọọ loye ninu ẹkọ imọ iṣegun ibilẹ.

Aarẹ ẹgbẹ naa to ba BBC Yoruba sọrọ, Ọjọgbọn Adedayo Faduyile sọ pe gbigba oye ninu eto iṣegun ibilẹ ni nileewe giga yoo ṣeranwọ ni ẹka eto ilera.

O yanana ẹ pe a gbọdo gbe igbesẹ to yẹ lori ayẹwo gidi nipa odinwọn ki o to le di ohun tawọn le maa lo lorilẹ-ede Naijiria.

O ni gbigba ẹkọ lori oogun ibilẹ yoo dẹkun ọpọ awọn eeyan ti ko yẹ ki wọn wa nibi iṣegun ibilẹ ti wọn wa nibẹ lọwọ yii.

Dokita Faduyile tun fikun ọrọ rẹ pe kikọ iṣegun ibilẹ ni ileewe giga fasiti yoo jẹ ki gbedeke wa lori odiwọn lilo ogun ibilẹ.

Aarẹ ajọ NMA fikun ọrọ rẹ pe kikọ oogun ibilẹ nileewe yoo jẹ kawọn ọmọ Naijiria ni itọju to peye eleyi ti yoo jẹ ki alaafia jọba.

O ṣalaye awọn to n ṣe oogun ibilẹ le tọ awọn olukọ imọ sayẹnsi ni ileewe sọna nitori ''iwe kọ ni gbogbo nnkaa, ọgbọn ori lo ṣe koko.''

Ṣugbọn Ọjọgbọn Faduyile ni aridaju gbọdọ wa pe bi o ṣe yẹ ki oogun ibilẹ ṣiṣẹ lo ṣe n ṣiṣẹ ko to le di wi pa awọn eeyan yoo maa kẹkọọ gboye lori rẹ ni ileewe giga fasiti.

Minisita keji fun eto ilera, Sẹnẹtọ Olọrunnibẹ Mamora lo kepe awọn ileewe giga fasiti ni Naijiria lati ṣagbekalẹ ẹkọ iṣegun ibilẹ fun eto ilera to peye ni Naijiria.

Sẹnẹtọ Mamora sọrọ naa nibi ayajọ oogun ibilẹ tọdun 2019 niluu Abuja.