Bobrisky: Ìléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàlàyé ohun tó gbé wọn dé ibi ìnáwó ọjọ́ ìbí

Bobrisky Image copyright Bobrisky

Gbogbo aye lo fẹrẹ mọ ọ tan, ọna ti olukuluku gba mọ ọ lo yatọ, Iyẹn Idris Okuneye, Bobrisky.

Ni ọjọ Abamẹta ni okiki kan nipa ayẹyẹ ọjọ ibi Bobrisky to waye lagbegbe Lekki Phase 1 nilu Eko.

Okiki to kan kii ṣe nipa awọn eekan atawọn eeyan jankanjankan to peju-pesẹ sibẹ ṣugbọn pẹlu bi ọgọrọ ọlọpaa tun ṣe ya bo ibi ayẹyẹ naa.

Ṣaaju ninu ọsẹ yii, bi ẹ ko ba gbagbe, ni Bobrisky ati alaga ajọ agbaṣaga lorilẹ-ede Naijiria, National Council for Arts and Culture, Ọtunba Oluṣẹgun Runṣewe ti ta ohùn si ara wọn.

Bi Runṣewe ṣe ni pe Bobrisky n ba oju orilẹ-ede Naijiria loju jẹ naa ni Bobrisky n da a lohun pe, o keere si nọmba nitori awọn to ju u lọ lagbo iṣejọba loun n ba dowo pọ.

Image copyright Bobrisky

Lẹyin ti ariwo sọ nile loko lori ohun ti ọlọpaa n wa ni ibi ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ; agbẹnusọ awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Bala Elkana ṣalaye pe awo iroyin kan to lu si awọn lọwọ lo gbe awọn lọ sibi ayẹyẹ naa.

Amọṣa, ọga ọlọpaa, Ẹlkana ko sọ ni pato awo iroyin to lu si wọn lọwọ naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti kọkọ fi ikilọ sita ṣaaju ni ibẹrẹ ọdun 2019 pe ki gbogbo awọn abẹya ara kan lo tete wa ibi gba.

Ẹwọn ọdun mẹrinl;a ni ofin kede fun igbeyawo akọ si akọ tabi abo si abo ni Naijiria.

Wọn ni nitori pe awọn ọlọpaa fẹ bẹrẹ si ni ko awọn ọkunrin to n ba ọkunrin lo pọ atawọn obinrin to n ba obinrin lo pọ si inu koto ọlọpaa.

Gẹgẹ bi a si ti ṣe gbọ, ọpọlọpọ awọn ọkunrin to n ba ọkunrin lo pọ atawọn obinrin to n ba obinrin lo pọ ni wọn peju pesẹ si ibi ayẹyẹ ọjọ ibi Bobrisky ti oun pẹlu jẹ akọ ti n ṣe iṣe abo.

Gbogbo igbiyanju BBC lati ba awọn agbofinro sọrọ lori iṣẹlẹ paapaa olobo ti wọn ni ẹnikan tawọn yii ja si pabo