ÌP&ID: Ẹgbẹ́ àgbáríjọpọ̀ ajàfẹ́tọ̀ọ́ fẹ̀hónú hàn l'Abuja lórí ìdájọ́ tó gbẹ́sẹ̀ lé $9.6bn ohun ìní Nàìjíríà

Awọn olufẹhonu han Image copyright Twitter/UK High Commission

Naijiria ko ni owo ti orilẹ-ede kankan le gba lasiko yii - Awọn oluwọde.

Agbarijọpọ ẹgbẹ ajafẹtọ kan ti wọn pe ara wọn ni Coalition of Civil Society group ṣewọde lọ si olu ileeṣẹ ilẹ Gẹeṣi l'Abuja.

Wọn lọ fẹhonu wọn han lori idajọ ileejọ to fun ileeṣẹ Process and Industrial Development laṣẹ lati gbẹsẹ le ohun ini orilẹ-ede Naijiria to le ni biliọnu mẹsan an dọla.

Awọn olufẹhonuhan naa ni iwọde naa yoo tẹsiwaju fun ọsẹ kan gbako ayafi ti ileẹjọ ọhun ba yi idajọ rẹ pada.

Awọn to n ṣewọde ọun mu orisiiriṣii beba dani ti wọn fi n beere lọwọ ijọba ilẹ Gẹẹsi pe ki wọn wa nnkan ṣe lori ọrọ naa.

Aarẹ ati akọwe ẹgbẹ to n ṣewọde naa, Etuk Williams ati Abubakar Ibrahim ṣapejuwe idajọ naa gẹgẹ idoju otitọ bo lẹ.

Wọn tun ni idajọ ọhun tabuku Naijiria gẹgẹ bi orilẹede olominira.

Wọn rọ Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson pe ko gbaruku ti Aarẹ Muhammadu Buhari lati gbogun ti iwa ajẹbanu.

Lẹyin wakati kan ti wọn ti ṣe ifẹhonu han ni wọn fun oṣiṣẹ olu ileeṣẹ ilẹ Gẹẹsi kan ni lẹta ti wọn mu dani.

Bakan naa wọn tẹsiwaju ifẹhonu han wọn lọ si olu ileeṣẹ orilẹ-ede Ireland lagbegbe Maitama l'Abuja.