Ìdájọ́ ọmọ mi tó gbé àdó ìkú wọ bàálù le púpọ̀, ẹ bá mi wòó ṣe - Bàbá Mutallab
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Mutallab: Bàbá rẹ̀ ní ọmọ òun ti kábàmọ́ọ̀ ìwà tó wù, kí wọn ṣàánú rẹ̀

Ibanujẹ nla gbaa ni fun obi lati ri ọmọ rẹ ko maa se idajọ ẹwọn gbere nitori ọmọ ẹni kii buru, ka le fun ẹkun pa jẹ.

Bayi ni ọrọ ri pẹlu baba ọmọkunrin to gbe ado oloro wọ baalu to n lọ silu oyinbo lọjọ keresi lọdun 2009, ti orukọ rẹ n jẹ Umar Farouk Abdulmutallab.

Lasiko ti baba rẹ n ba BBC sọrọ nibayi to n lọ ọdun mẹwa ti isẹlẹ naa waye, baba Mutallab ni idajọ ‘ma ri oorun’ ti wọn fun ọmọ oun ti lagbara ju, yoo si dara ki awọn alasẹ ba woo se.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo sisọ loju rẹ pe loore koore ni oun n lọ wo ọmọ naa, ti oun si n ba sọrọ, o si ti foju han pe Mutallab ti kabamọ iwa to hu ọhun.

Baba Mutallab wa rawọ ẹbẹ sawọn alasẹ pe ki wọn tun idajọ ti wọn se fun ọmọ oun yẹwo bi o tilẹ jẹ pe lootọ lo gba pe oun jẹbi gbogbo awsn ẹsun ti wọn ka si lọrun.

O fikun pe oun ko kabamọ pe oun pe akiyesi awọn alasẹ si ihuwasi ọmọ oun ko to di pe asiri rẹ tu, ti oun si n gbadura fun pe ko jade lẹwọn boya loju aye oun ni abi lẹyin rẹ.