Ẹ̀ wo àwòrán ìgbé ayé Robert Mugabe!

Àkójọpọ̀ àwọn àwòrán Robert Mugabe nígbà tó jẹ́ Ààrẹ ilẹ̀ Zimbabwe:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Adari Ẹgbẹ oselu African National Union (Zanu) Robert Mugabe ni Olotu Orilẹede Zimbabwe, lẹyin ti wọn fopin si eto isejọba awọn alawọ funfun lorilẹede wọn.
Image copyright PA
Àkọlé àwòrán Mugabe nikan ni adari ti orilẹede Zimbabwe ti ni lati igba ti wọn ti gba ominiran . Oun re ni Osu Kẹta, ọdun 1980, pẹlu ọmọọba ilẹ Wales ati Akowe ijọba Ilẹ Gẹẹsi nigba naa loun, Lord Carrington.
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mugabe di ilumọọka lasiko to jẹ adari ikọ ọmọọgun gorilla to n koju awọn alawọ funfun ti wọn jọba le wọn lori.
Image copyright PA
Àkọlé àwòrán Mugabe re e pẹlu Olootu Ilẹ Gẹẹsi, Margaret Thatcher ni ọdun 1980.
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mugabe wa ni ipo Adari pẹlu Aarẹ Canaan Banana titi di ọdun 1987, ti o gba ijọba gẹgẹ bi aarẹ.
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ orilẹede Zimbabwe sọ wi pe nkan bẹrẹ si ni wọ́ fun Mugabe nigba to fẹ akowe rẹ, Grace ni ọdun 1996.
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọdun 1995 ni Mugabe se ipade po pẹlu Aarẹ orilẹede Amerika nigba naa, Bill Clinton lasiko ti ọrọ aje wọn dẹnukọlẹ.
Image copyright PA
Àkọlé àwòrán Mugabe fi ẹsun kan awọn alawọ funfun lorilẹede Mugabe ati Ilẹ Gẹẹsi fun isoro to koju orilẹede Zimbabwe nitori awọn lo ko wọn lẹru.
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Lati ọdun 2000 si iwaju ni awọn ọmọlẹyin ikọ guerrillas tẹlẹri bẹrẹ si ni sisẹ ikọ ologun fun aarẹ Mugabe.
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ikọ Guesrillas yii se ikọlu si ẹgbẹ alatako, ti wọn si danu sun awọn oko to jẹ ti awọn alawọ funfun.
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán O le ni ọgọrun eniyan ti ẹmi wọn lọ si ipolongo idibo ni ọdun 2003, ti o fi Mugabe silẹ ni ipo, lẹyin to ni awọn orilẹede alawọ funfun n gbimọ lati gba ipo ni ọwọ oun.
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Mugabe to jẹ ọmọ ijọ Aguda sọ wi pe adura oun gba nigba ti oun rẹyin awọn ọta oun, ti wọn si gba oko pada lọwọ awọn alawọ funfun.
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ni Osu Kẹta, ọdun 2008 ni awọn eniyan mura lati dibo yan Aarẹ orilẹede Zimbabwe pẹlu ọrọ aje orilẹede naa naa to dẹnu kọlẹ, ti o si dabi ẹni pe ohun gbogbo ko sẹnu ire fun Mugabe.
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Lẹyin ti Mugabe kuna ninu idibo akoko, ti alatako rẹ, Morgan Tsvangirai si bori, Mugabe fariga pẹlu ibura wi pe Olorun nikan lo le yọ oun nipo. Tsvangirai fi ipo silẹ fun lẹyin ti wọn se ikọlu si awọn alatilẹyin rẹ.
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Eto idokowo orilẹede naa tunbọ dẹnukọlẹ si, eyi to mu ki Mugabe gba lati se ijọba pẹlu alatako rẹ, Morgan Tsvangirai to di Olootu ijọba.
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ni ọpọ igba lo ma n jẹ iroyin ẹlẹje wi pe Mugabe ti ku, amọ ni ọdun 2011 ni Wikileaks fi lede wi pe Aarẹ naa ni arun jẹjẹrẹ oju ara ọkunrin.
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mugabe ni ẹni ọdun mejidinlaadọrun sọ wi pe ọpọ igba ni oun ti ku, nitori iroyin ẹlẹjẹ ti o ma n sọ wi pe oun ti ku. O tilẹ fi se awada wi pe oun tobi ju Jesu Kristi lọ nitori pe oun ti ku lọpọ igba, amọ igba kan soso ni Jesu ku, ti o si jinde.
Image copyright Keystone / Getty Images
Àkọlé àwòrán Robert Mugabe ti wọn bi ni ọdun 1924 fi aye silẹ ni ọdun 2019.