Seyi Makinde: Ẹni tó bá pín owó àkánṣe iṣẹ́ nínú ìjọba mi yóò gé ìka jẹ

Gomina Seyi Makinde Image copyright @seyiamakinde

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti fọgba yangan o.

Makinde ti tu aṣiri bi wọn ṣe n pin owo ti wọn ba ya sọtọ fun akanṣe iṣẹ ni ipinlẹ Ọyọ, lasiko ijọba gomina ana ni ipinlẹ naa.

Makinde ni bi gomina ana ṣe n gba, ni iyawo rẹ naa n gba owo bọbẹ lara owo ti wọn ba ya sọtọ fun ṣiṣe akanṣe iṣẹ agbaṣe ni ipinlẹ Ọyọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Ṣeyi Makinde sọ ọrọ yii o lasiko to n fọrọ werọ pẹlawọn araalu lori ọgọrun ọjọ iṣejọba rẹ.

Ṣe ẹ ranti pe Seyi Makinde funrarẹ lo sọ ko to de ori oye pe, gbogbo ohun ti araalu n foju wo gẹgẹ bi aṣiri imulẹ ninu iṣejọba ni oun yoo ṣi aṣọ loju rẹ ni kiakia.

"Ohun ti a ba nilẹ ni pe ki wọn gbe owo jade fun iṣẹ agbaṣe ki o jẹ pe ida mẹwa ninu ọgọrun owo ti wọn gbe jade ni wọn yoo fi ṣe iṣẹ akanṣe ti wọn tori gbe owo naa jade.

"Ohun ti wọn sọ fun wa ni pe, ilaji owo ti wọn gbe jade fun iṣẹ agbaṣe ọhun ni yoo pada si apo gomina, ida ọgbọn ninu ọgọrun owo yoo lọ si ọdọ ẹni to fi ọwọ si gbigbe owo naa jade.

Ninu ida ọgbọn yii ni wọn yoo si tun ti yọ ida mẹwa fun iyawo gomina. Ṣugbọn emi ti wa sọ fun wọn pe, ẹnikẹni to ba san iru aṣọ bẹẹ ṣoro labẹ iṣejọba mii yoo jẹ iyan rẹ ni'ṣu."

Image copyright @seyiamakinde

Gomina Makinde ni igbesẹ to lamilaaka ni iṣejọba oun n gbe bayii, lati dẹkun iwa jẹgudujẹra lẹnu iṣejọba.

O ni idi gan an niyi ti oun fi gbe aba kan kalẹ fun idasilẹ ajọ ti yoo maa gbogun ti iwa ijẹkujẹ ni ipinlẹ Ọyọ.

Lootọ gomina Makinde ko darukọ ẹnikẹni ṣugbọn ọpọ araalu lo ti n na ika si Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi, nitori pe oun naa lo ṣe ijọba ki Makinde to gba ipo naa ni oṣu karun ọdun yii.