41 Days Fasting: Akẹ́kọ̀ọ́ kan gba ààwẹ̀ ọlọ́jọ́ 41, ó dèrò ilé ìwòsàn

Ẹlẹsin kan n tẹwọ adura Image copyright Getty Images

Laipẹ yii ni iroyin gbalẹ kan pe akẹkọ kan nile ẹkọ fasiti ipinlẹ Ebonyi, Ikechukwu Oke, gba aawẹ ọlọjọ mọkanlelogoji, to si ti ru kan egungun.

Idi ree ti awọn ẹbi rẹ se gbe digbadigba lọ sile iwosan fun itọju nigba ti agọ ara rẹ ko mokun mọ

Iwadii fi ye wa wi pe, akẹkọọ naa ko ṣẹṣẹ maa gba iru aawẹ bẹẹ nitori ogun idile to ni oun n koju.

Ṣugbọn ọpọ eeyan to gbọ nipa iroyin yii lawọn oju opo ikansira ẹni lori itakun agbaye lo n fi abuku kan Ikechukwu pe alailero ati ope ninu ẹsin ni.

Amọ ọna lati wadi ohun gbogbo daju nipa ohun ti eto ilera sọ lori aawẹ gbigba lo mu ki BBC Yoruba kan si dokita oyinsegun oyinbo kan lati salaye boya o dara fun ara lati gba aawẹ ọlọjọ gbọọrọ bii eyi.

Dokita Ọlalekan, lasiko to sọrọ lori aawẹ gbigba ni ko si ohun to buru ninu rẹ eyiun ti o ba ti ba ara wa mu.

O fikun pe onikaluku ẹda kọọkan lo gbọdọ mọ iwọn aawẹ ti ara rẹ lee gba, ko maa ba fa akoba si ilera rẹ nitori pe ohun ti Taye lee se, Kẹhinde lee ma lee se.

Image copyright Getty Images

Onimọ isegun naa ni agọ ara ẹnikọọkan lo ni banki to n fi suga ati ounjẹ afaralokun pamọ si, ti ko si gbọdọ dinku abi ko tan rara.

Olalekan sọ siwaju pe " Akoba to wa ninu gbigba awẹ slọjọ gbọọrọ naa ni pe ewu nla n bẹ fun ẹni to ba gba aawẹ naa ti adinku ba fi ba iye odiwọn suga ati ounjẹ afara lokun to wa nipamọ ninu ara rẹ abi ko tiẹ tan patapata nigba ti onitọun ko ba jẹ ounjẹ miran dipo eyi to n lo nitori pe o n gba aawẹ."

O wa gba awọn eeyan nimọran pe lootọ ni ko si ohun to buru ninu ki eeyan gba aawẹ lati fi wa oju Ọlọrun amọ ẹnikọọkan gbọdọ mọ iye aawẹ ti ara rẹ lee gba lai fa akoba si agọ ara, o si lee jẹ ọjọ kan, ọsẹ kan abi ju bẹẹ lọ, ti okun ara rẹ ba ti gbe.

Ṣugbọn o ṣalaye wi pe, ti ara ko ba ti ni anfani lati tẹsiwaju mọ, o di dandan ki a mu iru aawẹ bẹẹ wa si opin.

O ni ti irufẹ ẹni bẹẹ ko ba dẹkun aawẹ naa nigba ti gbogbo eroja ara ko ba le gba mọ, o ṣeeṣe ki ẹmi bọ lara iru ẹni bẹẹ lairo tẹlẹ.CA