Busola Dakolo: Mílíọ́nù mẹ́wàá náírà tí a béèrè kì í ṣe owó gbà má-bínú

AWORAN BUSOLA DAKOLO Image copyright BUSOLA DAKOLO
Àkọlé àwòrán Busola Dakolo: Mílíọ́nù mẹ́wàá náírà tí a béèrè kì í ṣe owó gbà má-bínú

Agbẹjọro Busola Dakolo ti sọ pe, irọ balau ni pe onibara oun fẹ gba miliọnu mẹwaa Naira gẹgẹ bi owo gba ma-binu lọwọ oludasilẹ ijọ COZA, Biọdun Fatoyinbo.

Pelumi Olajengbesi ti o jẹ agbẹjọro to n ṣoju Dakolo ni owo naa jẹ owo iṣẹ oun gẹgẹ bi agbẹjọro Busọla ni.

O salaye pe "ahesọ ọrọ ni pe onibara mi beere owo gba ma-binu lati ọwọ Pasitọ Biodun Fatoyinbo."

"Idi ti onibara wa ṣe pe Fatoyinbo lẹjọ ni ki ile ẹjọ le e ṣe idajọ ti o tọ, ati lati ran awọn elomiran ti o lee wa niru ipo yii lọwọ."

O ni o ṣe pataki lati fi ye awọn eniyan pe, miliọnu mẹwaa naira ti awọn oniroyin n sọ jẹ owo iṣẹ ti awọn agbẹjọro n ṣẹ lori ipẹjọ naa.

Àkọlé àwòrán COZA: Iléejọ́ Abuja ké si Fatoyinbo ati Busola Dakolo pé kí wọ́n yọjú.

COZA: Ṣe Ilé ejọ́ Abuja ti ké si Fatoyinbo ati Busola Dakolo pé kí wọ́n yọjú?

Saaju lawọn iwe iroyin kaakiri Naijria ti gbe iroyin pe ile ejọ giga nilu Abuja ti ni ki pasitọ Biodun Fatoyinbo ati Arabinrin Busola Dakolo foju ba ile ẹjọ laarin ọjọ mẹrinla.

Amọ, agbẹjọro Busọla Dakolo ti fesi pe ko si ootọ ninu ọrọ naa.

Ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aje o ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n ṣe iwadii ọrọ naa.

O tẹnumọ pe ile ẹjọ giga lAbuja ko ti fiwe pe Busola Dakolo ati Pasito Biodun Fatoyinbo titi di bi a ti ṣe n sọrọ yi.

Ẹwẹ, Pasito Fatoyinbo naa ti fesi si ọrọ naa loju opo Instagram pe ile ẹjọ ko ti ranṣẹ pe oun naa

Gbajugba ayaworan lo fi ẹsun kan Biodun Fatoyinbo pe o fipa ba oun lo pọ ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin ti Fatoyinbo si fariga pe ọrọ ko ribẹ.

Pasitọ Biodun Fatoyinbo ni oludasilẹ ile ijọsin Common wealth of Zion Assembly.

Agbẹjọrọ lati ile iṣẹ Pelumi Olajengbesi and Co lo gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ lorukọ Busola Dakolo.

Opọ awọn eniyan ni wọn ti n woye ibi ti ọrọ naa yoo jasi.