Offa Descendant Union: A dupẹ́ lọ́wọ́ àwọn agbófinró tó dóòlà àwọn ọmọ Ọffa lọ́wọ́ ajínigbé

Awọn gende agbebọn. Image copyright @NigerianPolice
Àkọlé àwòrán Kí a tó sanwó ajínigbé ní àwọn agbófinró dóòlà ọmọ Ọffa mẹ́fà -ODU

Ori ti ko awọn ọmọ bibi ilu Offa mẹfa ti awọn ajinigbe jigbe yọ ninu igbekun awọn alaburu.

Lowurọ ọjọru ni awọn agbofinro tu wọn silẹ lọwọ awọn to ji wọn gbe loju ọna Kaduna si Abuja.

Alukoro ẹgbẹ ọmọ bibi ilu Offa, Maruf Olalekan Ajenifuja to fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC ni awọn ko san owo itanran kankan fun awọn ajinigbe ki wọn to tu wọn silẹ.

O mẹnuba iṣẹ akọni ti awọn ọṣiṣẹ eleto aabo gbogbo pawọpọ ṣe ki awọn oniṣẹ ibi ajinigbe to tu awọn ọmọ wọnyii silẹ.

Ogbeni Maruf ni: ''Looto la ni erongba lati san owo fawọn ajinigbe naa ṣugbọn ki a to san owo naa lawọn agbofinro tu wọn silẹ''

O ṣalaye pe awọn eeyan meje ni wọn ribi doola ẹmi wọn ti a si ri ọmọ bibi ilu Offa ninu wọn.

Ajenifuja wa dupẹ lọwọ gbogbo awọn ara ilu Offa to fi mọ awọn to duro ti wọn lasiko ijinigbe yi.

BBC Yoruba gbiyanju lati beere lọwọ alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Kaduna boya wọn ri awọn ajinigbe naa mu ṣugbọn ko gbe aago ipe rẹ titi di igba ti a fi gbe iroyin yii jade.

Kin lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Lọjọ Abamẹta to kọja ni wọn ji awọn ọmọ Offa yii gbe.

Ẹgbẹ ọmọ bibi ilu Offa lawọn ṣi n dunadura pẹlu awọn ajinigbe lati doola ẹmi awọn ọmọ ilu Offa mẹfa ti wọn ji gbe.

Alukoro fẹgbẹ ọmọ Ilu Offa tẹlẹri, Olayemi Olaboye lo ṣalaye ọrọ yi fun ile iṣẹ BBC Yoruba ninu ifọrọwanilẹnuwo.

Olaboye to tun jẹ akọwe igbimọ alaabo ilu Offa fidi ọrọ naa mulẹ pe awọn ti gburo lati ọdọ awọn ajinigbe naa ti wọn si ti sọ pe awọn fẹ gba owo lori awọn ti wọn jigbe.

''Gbogbo igbiyanju to wa ni ikapa wa la n gba, ti a si ti sọ fun awọn mọlẹbi awọn ti wọn jigbe pe ki wọn pa ọkan pọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán T'obìnrin àti t'ọmọde ni wọn ń jigbe kaakiri bayii

Titi di bi mo ti ṣe n ba yin sọrọ yi, a ko tii ri ibi doola wọn, amọ, a ni ireti pe wọn yoo pada wale layọ ati alaafia''

Lalẹ ọjọ Abamẹta ni iroyin ijinigbe naa kan gẹgẹ bi alaye ti Olaboye ṣe.

O ni awọn ti wọn farakasa iṣẹlẹ naa wọkọ nilu Offa ti wọn si n lọ si Katsina ṣugbọn nigba ti wọn de agbegbe kan ti wọn n pe ni Ajana laarin Abuja si Kaduna ni wọn ko si ọwọ awọn ajinigbe.

Muideen Ibrahim, to jẹ akọwe apapọ ẹgbẹ naa ni ohun to ṣe pataki sawọn ni lati doola ẹmi awọn ti wọn jigbe.

Image copyright Facebook/hrmobaolofa
Àkọlé àwòrán Oloffa Ilu Offa

''Ẹni to n ba wa dunadura pẹlu awọn ajinigbe ko ti i pe wa pada lati sọ iye ti wọn fẹ gba ṣugbọn ohunkohun to ba gba la ṣetan lati ṣe ki wọn ba le e doola ẹmi wọn''

Ẹni ti ọrọ ijinigbe yi ba kan lo mọ ni Naijiria ṣugbọn lẹnu ọjọ mẹta yi, iṣẹlẹ ijinigbe loju ọna Kaduna si Abuja jẹ ohun to n ko awọn arinrinajo laya soke.

Ile iṣe ọlọpaa Naijiria lawọn kaju osunwọn lati koju ipenija ijingbe yi amọ ko jọ bi pe ipa wọn ka awọn ajinigbe naa ti iroko wọn ṣebi ẹni n pẹka si.