Atiku vs Buhari: Adájọ́ yóò ṣẹ̀dájọ́ lóní lórí ìbò ààrẹ Naijiria

Aarẹ Muhammadu Buhari ati Atiku Abubakar Image copyright @Mhizta_Daniels
Àkọlé àwòrán Atiku vs Buhari: Adájọ́ yóò ṣẹ̀dájọ́ lóní lórí ìbò ààrẹ Naijiria

Loni ni ileẹjọ to n ṣegbẹjọ ẹsun idibo yoo ṣedajọ lori ọrọ idibo aarẹ to waye losu keji ọdun yii l'Abuja.

Agbẹnusọ fun ileẹjọ tn s ṣteto igbẹjọ ẹsun idibo, Sadiat Kachalla, lo fi ọrọ naa lede.

Ṣaaju ni Atiku Abubakar ti ẹgbe oṣelu PDP ti pe aarẹ Muhammadu Buhari, ẹgbẹ oṣelu APC ati ajo INEC lẹjọ, lori esi ibo sipo aarẹ to waye lọjọ ketalelogun, oṣu keji ọdun yii..

Gẹgẹ bi ofin to jẹ mọ eto idibo nilẹ Naijiria ti ọdun 2010 ṣe fi lelẹ, ile ẹjọ gbọdọ ṣedajọ lori ipejọ naa, lẹyin ti Atiku ti lọ ile ẹjọ lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta ọdun yii, laarin ọgọsan an ọjọ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keji ọdun yii ni ajọ INEC kede pe Muhammadu Buhari, ti ẹgbẹ APC, lo jawe olubori ninu idibo ọhun.

INEC ni Buhari ni ibo ti iye rẹ jẹ 15,191,847, nigba ti ẹni to n sare tẹle lẹyin, Atiku Abubakar ni ibo ti iye rẹ jẹ 11,262,978.

Lẹyin esi ibo naa jade ni Atiku fariga pe oun lo bori ninu idibo naa.

Image copyright Twitter/HOTCUBE2
Àkọlé àwòrán O ni ibo ti oun fi pọ ju ti aarẹ Buhari le ni miliọnu kan ati aabọ.

Atiku ni ohun ti ẹrọ ayarabiaṣa ajọ INEC gbe jade yatọ kedere si esi ti ajọ naa gbe kalẹ lori esi idibo naa.

O ni ibo ti oun fi pọ ju ti aarẹ Buhari le ni miliọnu kan ati aabọ.

Gẹgẹ bi iṣiro rẹ, ibo ti oun ni jẹ 18,356,732, nigba ti ibo aarẹ Buhari jẹ 16,741,430, fun idi eyi, ki ile ẹjọ kede oun gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo naa.

Awọn agbẹjọro Atiku, ti Ọmọwe Livy Uzoukwu n soju ṣalaye fun ile ẹjọ to n ṣegbẹjọ ẹsun idibo naa pe, ajọ INEC fun Aarẹ Buhari ti ẹgbẹ APC ni ibo ti ko yẹ laimoye ọna.

Wọn ni eyi to fi jẹ pe, iye ibo ti awọn oludibo di yatọ si iye ibo ti ajọ naa gbe fun aarẹ Buhari, ti o si gbe oludije ọhun wọle sipo leekeji.

Image copyright Twitter/BestiaresG
Àkọlé àwòrán Ta ni yoo tẹsiwaju lati tukọ Naijiria lẹyin idajọ?

Atiku tẹ siwaju pe yatọ si esi ibo ipinlẹ mọkanla ti oun ko gba wọle, Buhari parọ lori ipele iwe ti o ka nigba ti o n dije fun ipo aarẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe olupẹjọ naa ni oun yoo pe irinwo awọn o-ṣoju mi koro lati fidi ẹjọ rẹ mulẹ, nigb ati yoo pari awijare rẹ lọjọ kankandinlogun, oṣu keje, ọdun yii, awọn mejilelọgọta pere lo yọju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSẹ́nẹ́tọ̀ Femi Okunronmu sọ pé Atiku ló le tún Nàìjírìa ṣe

Sugbọn adari awọn agbẹjọro fun aarẹ Buhari, oloye Wole Olanipekun fesi pe, ko si ninu ofin orilẹ-ede Naijiria fun ẹnikẹni to ba fẹ dije fun ipo aarẹ lati fi iwe ẹri pe o lọ sile iwe han gẹgẹ bi oun amuyẹ lati di aarẹ.

Image copyright Twitter/@MBuhari
Àkọlé àwòrán Emi ko nilo iwe ẹri ki n to le dije

Wole Olanipekun tun ṣalaye siwaju pe, oun kan ṣoṣo ni ofin fidi rẹ mule, eyii naa ni pe, ki ẹnikẹni to ba fẹ lati dije fun ipo aarẹ kawe, eyi ti Buhari ni amuyẹ rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ẹ dìbò fún Atiku nílẹ̀ Yorùbá'

Agbẹjọro fun ajọ INEC, Yunus Usman ni, ẹjọ ti olupẹjọ naa pe ko lẹsẹ n lẹ, nitori ajọ INEC tẹle gbogbo ilana ti ofin to rọ mọ eto idibo ti ọdun 2010 gbe kalẹ.

Ni ọrọ tirẹ, Lateef Fagbemi to jẹ agbẹjọro fun ẹgbẹ APC ni ejọ ti Atiku pe fuyẹ nilẹ bi iyẹ ni, nitori olupẹjọ naa ko lee ṣatilẹyin ẹjọ to pe.