Ìwádìí kan ní Ilééṣẹ́ Facebook leè mọ ìgbà tí àwọn tó wà lójú òpó wọn bá ní ìbálòpọ̀

Aworan takọ tabo lori ibusun Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ilééṣẹ́ Facebook mọ ìgbà tí àwọn tó wà lójú wọn ń nií ìbálòpọ̀

Awọn alaye ikọkọ kan, lara eyii ti igba ti eeyan ba n ni ibalopọ, ni ileeṣẹ Facebook lee mọ.

Iwadii ti ileeṣẹ kan ṣe ti fi han pe, ileeṣẹ Facebook lee mọ igba ti awọn to wa loju opo ọhun ba n ni ibalopọ, paapaa julọ, awọn obinrin.

Ileeṣẹ Privacy International to wa nilu ọba lo ṣe iwadii lori awọn oun kan, lori ẹrọ ayelujara ti o ma n ṣe atọka igba ti obirin yoo ṣe nkan oṣu.

Iwadii naa fi han pe, awọn ohun to wa lori ẹrọ alagbeka to n ka igba ti obinrin ba n ṣe nkan oṣu yii, maa n pin lara iwadii wọn pelu ileeṣẹ Facebook.

Lara awọn iwadii ti ẹrọ naa ṣe ni lati mọ igba ti nkan oṣu maa n de, ati iru iriri ti awọn to ba n ṣe nkan oṣu n ni.

Awọn oun to wa lori ẹrọ alagbeka to n ka igba ti obirin ba n ṣe nkan oṣu yii lee mọ oun ti eniyan jẹ, ohun ti wọn mu, alaye nipa ibalopọ ati iru ohun ti won n lo lati ṣe nkan oṣu naa.

Awọn esi iwadii yii lo maa n jẹ ki wọn lee sọ igba ti eeyan lee loyun ati igba ti nkan oṣu miran lee yọju.

Ọna ti awọn ohun to wa lori ẹrọ alagbeka yii fi n pin alaye ikọkọ yii fun ileeṣe Facebook jẹ nipa oun eelo kan ti wọn pe ni SDK.

Ileeṣẹ Privacy International ni awọn ohun elo ori ẹrọ alagbeka bii Period Tracker, Period Track Flo ati Clue Period Tracker kii pin abajade iwadii wọn pẹlu Facebook.

Sugbọn awón akẹgbẹ won mii bii Maya, MIA ati My Period Tracker maa n pin iwadii wọn pelu Facebook.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni