Omijé bọ lójú mí nígbà tí wọn n kọ orin ilẹ wà
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Xenophobia: Allen Onyeama ní 300 mílíọ̀nù náírà ní òun fí gbé àwọn ọmọ Nàìjíríà wálé

Yin ni yin ni,ki ẹ ni baa le ṣe mi,bẹẹ lọrọ ri ti a ba yẹ ọrọ ọmọ Naijiria to ṣagbatẹru dida awọn eeyan pada wale lati orileede South Africa.

Tijo tayọ lawọn to dari fi balẹ silu Eko ti awọn aṣoju ijọba Naijiria si wa sda wọn ni kaabọ.

Ṣugbọn gbogbo ati ranmu gangan ipadawasile wọn ko ṣẹyin gangan oludari ati alaga ileeṣẹ ọkọ ofurufu Peace Airline,Allen Onyeama.

Iru iwa ifarajin bayi ṣọwọn lawujọ ti pupọ awọn ọmọ Naijiria si ti n kan sara si fun igbesẹ to gbe yi.

Ninu ọrọ rẹ pẹlu awọn akọroyin,Onyeama ni aifẹ ki iya jẹ awọn ọmọ Naijiria lo mu ki ohun nawo nara lati ri pe wọn pada wa si Naijiria layọ ati alaafia.

''Ọọdunrun miliọnu Naira ni mo na lati ri wi pe gbogbo eto to ki wn ba le pada wa sile.Mo pinu lati ran ijọba Naijiria ati awọn eeyan lọwọ nitoripe bi mo ba ku,mi o ni gbe owo lọ si ọrun''

Loju opo Twitter ati kaakiri oju ayelujara lawọn eeyan ti n kan sara si arakunrin yi ti pupọ si kun fun adura ki ọna rẹ ma gbooro si

Kini ipa ti ijọba naa ko

Abikẹ Dabiri Erewa ti o jẹ Alaga ajọ ti o n ri si ọrọ ọmọ Naijiria loke okun kede iranwọ ijọba Naijiria fawọn to ṣeṣe tajo de naa.

Lara ọhun to ni ijọba yoo fun wn ni kaadi ipe ti wọn fi iye owo ẹgbẹrun lọna ogoji sinu rẹ.

Bakanna lo ni awọn yoo dawọn loko owo ti wn yoo si gba owo ọkọ pada si ilu wọn.

Pasitọ Suleman naa loun yoo gbe awọn ọmọ Naijiria wale

O jọ pe igbesẹ ti Allen Onyeama gbe yi ti ṣe koriya fawọn miran lati nawọ iranwọ sawọn to fẹ wale lati South Africa.

Lara awọn to wo awokọṣe rẹ ni Apostle Sleman to nioun yoo san owo tikẹti eeyan ogun lati South Africa wa si Naijiria.