Ọdọ́bìnrin kan dáná sun ara rẹ̀ lẹ̀yin tí àwọn òbi kọ̀ fún lati fẹ́ ọlọ́kadà

Maapu oril#e-ede naijiria Image copyright @others

Ọdọbinrin kan, Aisha Aminu, ni ariwa iwọ-oorun ipinlẹ Zamfara, ti da epo bẹntiro le ori ara rẹ to si dana sii.

O gbe igbesẹ naa léyin ti awón obi rẹ kọ fun lati fẹ ololufẹ rẹ to jẹ ọlọkada.

Aisha sọ fun ileeṣe BBC pe, idi ti oun fi hu iru iwa yii ni pe, yoo ṣoro fun oun lati wa laye laisi pẹlu ololufẹ oun yii.

Aminu Mohammed, to jẹ baba Aisha ṣalaye fun BBC pe, idi ti oun fi lodi si ere ifẹn naa ni pe akuṣẹ ni okunrin ti Aisha nifẹ si.

Aminu ni "Nigba ti ko ni owo lọwọ ni a sọ fun un pe ko fi ọmọ wa silẹ, ki ọmọ wa lee ri elomiran to ṣetan lati fẹ"

O tẹsiwaju pe, "A kọ lero pe Aisha nifẹ okunrin naa to bẹẹ, titi di igba ti o dana sun ara rẹ ki oto di pe awọn ara adugbo ba wa pa ina naa."

"Nigba ti a bii idi ti o fi hu iru iwa yii, o ni ifẹ ti oun ni si okunrin naa lo fa, ati pe oun ko fẹ di oni nabi ni oun ṣe dana sun ara oun."

Aisha salaye fun BBC pe, ọlọkada ni okunrin naa, ti ko si sọ pe oun ko ni owo lati fẹ oun.

O ni "Lẹhin ti mo gbọ pe o sọ fun awọn obi mi pe oun ko ni owo, ti wọn si ni ko fi mi silẹ ni mo pinnu pe iku ya jẹsin lọ."

Iṣẹlẹ naa ti mu ki Aisha ṣeṣe lọwọ, lẹsẹ ati lẹyin, sugbón o ti n gba itọju bayii.