Asòfin Kenya fẹ́ fi òfin de isó yíyà nínú ọkọ̀ bàlúù

Lilian Achieng Gogo Image copyright PARLIAMENT OF KENYA
Àkọlé àwòrán Lilian Achieng Gogo ni iso ma n da ija silẹ ninu ọkọ baluu

Ọkan lara awọn aṣofin nile igbimọ aṣofin Kenya ti fẹ ki ijọba lorilẹ-ede naa gbe ofin kalẹ, ti yoo ran awọn oṣiṣẹ inu ọkọ baluu lọwọ lati fi iya jẹ awon to ba n yaso ninu ọkọ ofurufu.

Lilian Achieng Gogo, to n soju ẹkun idibo Rangwe, ni iwọ oorun Kenya lo mu imọran yi wa nile aṣofin.

Lilian ni, awọn to n buso ninu ọkọ baluu lee ṣe ijamba fun ẹmi awọn elomiran ninu irufẹ ọkọ bẹẹ.

Aṣofin naa lo sọ ọrọ yii nigba ti o n dasi ọrọ to nii ṣe pẹlu atunyẹwo ofin to jẹ mọ iwa ibajẹ ninu ọkọ baluu.

Lara awọn imọran ti aṣofin naa fun ile aṣofin naa ni pe, ki ijọba fun awọn oṣiṣẹ inu ọkọ baluu laṣẹ lati fun awọn ero inu ọkọ baluu ni ogun to lee din iso ku ninu ọkọ baluu.

O wa ṣalaye pe iwa ki eeyan maa buso ninu ọkọ ofurufu jẹ oun to lee da ija silẹ.

Obirin naa tun fẹ ki awọn ibudokọ baluu din otin ku ninu ọkọ ofurufu.

Gẹgẹ bi ọrọ to sọ, o ṣalaye pe "bi awọn eeyan ṣe n mu ọtin ninu ọkọ baluu ku diẹ kaato.

Aṣofin naa wa pari ọrọ rẹ pe "Iwa imutinpara awọn eeyan loju ofurufu jẹ eyi to buru ju ti awọn to wa lori ilẹ lọ."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionXenophobia: Awọn ọmọ Naijiria n sọ ohun tó kàn lẹ́yìn ìpadàbọ̀ wọn