Election Tribunal: Lai Muhammed àti Oshiomole ní òfo ni ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn PDP yóò já sí

Muhammadu Buhari Image copyright @MBuhari

Ọrọ ko tii jẹ rodo lọ mumi lori idajọ ti igbimọ olugbẹjọ nipa awuyewuye ibo aarẹ gbe kalẹ, eyi to ni aroye oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oselu PDP, Alhaji Atiku Abubakar se niwaju igbimọ naa ko lẹsẹ nlẹ.

Lara awọn ohun to n jẹyọ lẹyin idajọ naa ni bi awọn alasẹ ati ẹgbẹ oselu APC lapapọ se n fi ẹgbẹ PDP to gbe wọn lọ sile ẹjọ se yẹyẹ.

Ijọba apapọ ilẹ yii, ti ẹgbẹ oselu APC n dari lo kọkọ kesi ẹgbẹ oselu PDP pe, ta ba le ni, ta ba ba ni iwọn laa bani se ọta mọ, yoo si dara ki PDP tete yara mọ agba lẹgbọn, ko si tọrọ aforiji lọwọ APC pe ko ma binu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Minisita feto iroyin ati asa, Lai Muhammed lo kede bẹẹ nigba to n fesi lori idajọ ti igbimọ olugbẹjọ naa gbe kalẹ lọjọru.

Image copyright @OfficialAPC

Sugbọn ẹgbẹ oselu PDP naa ti wa fesi pada fun pe yoo dara ki ẹgbẹ APC ati Lai Muhammed dunnu mọ niwọn lori idajọ naa, nitori ẹni to ba rin ẹrin igbẹyin lo ri ẹrin rin.

Akọwe ipolongo fẹgbẹ PDP Kọla Ọlọgbọndiyan salaye pe, idajọ ti APC n dunnu si yii ko lee jẹyọ nile ẹjọ to ga julọ lorilẹede yii, ti awọn si ti setan lati tun ẹjọ naa gbe dide nibẹ.

Image copyright @Atiku

Bakan naa ni alaga fun ẹgbẹ oselu APC, Adams Oshiomole naa ti n rẹrin keke si ọrọ PDP yii, to si ni bi wọn ba fẹ, wọn lee pe ẹjọ kotẹmilọrun ni kootu agbaye, ohun to si da ohun loju ni pe pabo naa ni ọrọ wọn yoo ja si.

Lasiko to n jẹwọ pẹlu awọn akọroyin nile ijọba nilu Abuja lẹyin to se ipade tan pẹlu aarẹ Buhari, Oshiomole salaye pe gbigba fun Ọlọrun ni isisnmi, ko si si ẹjọ kankan to tuntun ti PDP fẹ gbe lọ sile ẹjọ to ga julọ nilẹ yii nitori wọn ko ni ẹri kankan gidi to fi ẹsẹ mulẹ.