Xenophobia: Dabiri ní owóyàá, 9 gígábáítì afẹ́fẹ́ ayélujára àti káádì ìpè ₦40,000 nìjọba yóò fún wọn

Abike Dabiri n ki awọn arinrinajo lati South Africa kaabọ Image copyright @nidcom_gov

Ijọba apapọ Naijiria ti kede pe oun ko ni fi awọn ọmọ Naijiria to sẹsẹ de lati orilẹede South Africa silẹ lati jiya, ti oun yoo si pese eto iranwọ fun wọn.

Alaga fun ajọ to n riosi ọrọ awọn ọmọ Naijitia to wa lẹyin odi, Asofin Abikẹ Dabiri Erewa, lasiko to n tẹwọgba awọn sẹsẹde ọmọ ilẹ Naijiria naa ti wọn to mẹtadinlaadọwa niye, lo kede ọrọ itunu yii fun wọn.

Bakan naa lo sisọ loju rẹ pe ijọba ti gunle ijiroro pẹlu awọn alasẹ ile ifowopamọ kan lati gba owoya pẹpẹpẹ fun awọn eeyan naa to ba nifẹ si eto okoowo alabọde.

Image copyright @nidcom_gov

Yatọ si owoya naa, Dabiri tun ni awọn eeyan to sẹsẹ de lati South Africa naa yoo tun gba kaadi ati owo ipe lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ ti yoo to ẹgbẹrun lọna ogoji naira, to fi mọ afẹfẹ lilo oju opo ayelujara (Data), ti yoo to gigabaiti mẹsan eyi ti wọn yoo lo fun osu meji gbako.

Erewa tun lo akoko naa lati se sadankata sawọn alasẹ ileesẹ ọkọ ofurufu Air Peace fun ọwọ aanu ti wọn na lati ko awọn arinrinajo naa wale lai gba kọbọ.