South West Security: Akeredolu gbé ọkọ̀ ogun àti ọ̀gọ́fà ọ̀kadà kalẹ̀ fún Àmọ̀tẹ́kùn

Awọn ọdẹ ibilẹ Image copyright @BateFelix

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kede pe Amotẹkun ni wọn yoo maa pe orukọ ikọ to n pese aabo yika ilẹ Yoruba.

Bẹẹ ba gbagbe, lọjọbọ ni ipade eto aabo tun waye lati wa ojutu si awọn ipenija aabo to mẹhẹ to n ba ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria naa finra.

Awọn gomina ati ileesẹ ọlọpa si ti se agbekalẹ igbimọ alaabo kan ninu eyi taa ti ri awọn osisẹ agbofinro ati awọn ọmọ ẹgbẹ akọya fun ilẹ Yoruba, OPC, awọn ọdẹ ibilẹ ati awọn asọgbo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni itẹsiwaju abọ ipade naa, gomina Akeredolu ti gbe ọkọ nla Hilux bii ogun ati ọkada ọgọfa kalẹ fun ikọ Amọtẹkun naa, eyi ti yoo wagbo dẹkun fun awọn eeyan to n pagidina eto aabo lẹkun Kaarọ Oojire.

Image copyright @RotimiAkeredolu

Lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ, Kọmisana feto iroyin ati itaniji nipinlẹ Ondo, Donald Ojogo, salaye pe lati igbadegba ni igbogun ti eto aabo to mẹhẹ yoo maa waye, eyi ti awọn gomina n se atilẹyin fun.

Image copyright @RotimiAkeredolu

Ojogo ni gbogbo awọn ọdaran to n fi igbo boju lawọn yoo fin jade bii okete, ti wọn yoo si sa kuro tefetefe jinna sawọn ilu to wa nilẹ Yoruba.

Image copyright @RotimiAkeredolu

O wa fọwọ gbaya pe laipẹ ni wọn yoo si asọ loju eegun ikọ Amọtẹkun naa, ti wọn yoo si kawọ ikọlu awọn ọdaran to n waye nilẹ Kaarọ Oojire duro.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: