FUOYE : Segalink ní ìyàwó Fayemi ní ẹjọ́ jẹ́ lórí ikú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ FUOYE

Segalink

Ọrọ ikọlu laarin ikọ iyawo Gomina ipinlẹ Ekiti ati awọn akẹkọọ fasiti FOUYE ti gbọna miran yọ, pẹlu bi ajafẹtọmoniyan kan ṣe ni oun ṣetan lati pe Bisi Fayemi, iyawo Gomina ipinlẹ Ekiti lẹjọ.

Segun Awosanya ti ọpọ mọ si Segalinks loju opo Twitter ni lo kede bẹẹ.

Segalink ṣalaye pe ni ajọ Tech for Justice toun jẹ ọkan ninu wọn, pẹlu ifọwọsowọpọ National Human Rights Commission, awọn yoo pe iyawo Gomina lẹjọ lori iku awọn akẹkọọ naa.

Ninu fọnran fidio to fi kin ọrọ rẹ lẹyin, a ri ibi ti awọn eeyan kan ti n daro iku awọn ẹni ta ko le fi idi rẹ mulẹ bi wọn ti ṣe jẹ.

Gẹgẹ bi ohun ti wọn sọ ninu fọnran naa, wọn ni ibi isinku ọkan lara awọn ọmọkunrin ti ijọba Ekiti pa ni.

Ko pẹ ti Segalinks fi ọrọ akọkọ sita loju opo Twitter, lo tun fi omiran tẹle pe awọn kan ti n dunkoko mọ oun.

O ni aya oun ko ja ati pe, fidi idi ododo mulẹ nipa iṣẹlẹ naa ni o ṣe pataki si oun.

Titi di igba ti a n ṣe akojọpọ iroyin yi, iyawo gomina tabi ijọba ipinlẹ Ekiti ko ti fesi si ọrọ Segalinks.

Amọ ṣi saaju asiko yii, ni iyawo Gomina Bisi Fayemi ti ni ohun ko fawọn ọlọpaa laṣẹ lati yinbọn lu awọn akẹkọọ.

N kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nínú ikú akẹ́kọ̀ọ́ Fuoye, mo kẹ́dùn pẹ̀lú ẹbí wọn - Aya Fayemi

Iyawo gomina ipinlẹ Ekiti, Bisi Fayemi ti ni ko si otitọ kankan ninu ọrọ to n tan kaakiri pe, oun pasẹ fun awọn ọlọpaa lati sina bo awọn akẹkọọ Ile iwe giga Oye Ekiti, Fuoye to n fẹhọnu han.

Image copyright TWITTER
Àkọlé àwòrán Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fẹ́sùn kan ìyàwó gómìnà Ekiti wí pé òún ló pàsẹ kí àwọn ọlọ́pàá síná bo àwọn tó ń fẹ̀họ́nú hàn ní Oye Ekiti

Fayemi ninu atẹjade to fisita sọ wi pe, oun ko tilẹ pade awọn akẹkọọ kankan lọna nigba ti oun se ironilagbara kaakiri awọn ijọba ibilẹ mẹrin, ti ọkan lara wọn si waye ni Oye Ekiti.

O ni ohun ibanujẹ lo jẹ fun oun gẹgẹ bi iya pe, ọkan lara awọn akẹẹkọ sọ ẹmi nu ninu isẹlẹ naa, nitori naa ni oun se salaye ohun to sẹlẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Fayemi ni lootọ ni awọn gbọ pe awọn akẹkọọ n se ifẹhọnu han lori aisi ina ọba ni agbeegbe naa, amọ nigba ti oun de ibẹ, awọn akẹkọọ naa ti pari ifẹhọnu han wọn.

Image copyright TWITTER
Àkọlé àwòrán Bisi Fayemi: Èmi kọ́ ló pàsẹ fún ọlọ́pàá kó yìnbọn fún akẹ́kọ̀ọ́ Fuoye

Amọ o ni o seesẹ ko jẹ pe awọn janduku kan wọ ibi ti oun ti se ironilagbara, eleyii ti o jẹ ki awọn ọlọpaa koju wọn.

Amọ, o fikun wi pe ohun ko pasẹ fun awọn ọlọpaa lati yin ibọn lu ẹnikẹni, to si kẹdun pẹlu awọn ẹbi ati ara ti ọmọ wọn doloogbe ninu isẹlẹ naa.