BBNaija 2019: Khafi ní òun àti Gedoni kò ní àjọṣepọ̀ rárá

Gedoni ati Khaffi sun sori ibusun Image copyright @BBNaija

Ọlọ́pàá Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Khafi Kareem ti sọ wí pé òun kò tí ì bá ẹnìkẹ́ni ní àsepọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sí ìgbà yíí.

Khafi fi eyi lede lasiko ti wọn fun awọn ara ile Big Brother Naija laye lati sọ awọn nkan ti awọn eniyan ko mọ nipa wọn.

O ni ko si otitọ ninu iroyin to gba ẹrọ ayelujara kan wi pe oun ati Gedoni Ekpata ba ara wọn ni asepọ ninu ile Big brother Naija.

Khafi ni oun ko ba ẹnikeni ni asepọ lati le bori gbogbo awọn isoro to koju oun fun ọpọlọpọ ọdun.

Image copyright @BBNaija

Ọrọ naa di mimọ nigba ti Ike Oyeama ati Dianne sọ wi pe, awọn fi rọba idaboobo si ẹgbẹ ibusun Khafi ati Gedoni, ni awọn se sọ wi pe wọn lo o.

Gedoni naa ti o ti kuro ni ile Big Brother Naija naa sọ wi pe, ko si ibalopọ to waye laaarin oun ati Gedoni, amọ oun fẹran Khafi lọpọlọpọ.

Ọjọ Isinmi ni a mọ boya won yoo le Khafi kuro ni Big Brother Naija, nitori awọn ara ile ti fi orukọ rẹ silẹ gẹgẹ bi ẹni ti wọn yoo le kuro ninu ile.