Ọdún ìjẹṣu 2019: Àwọn ọmọ Ilara yarí,torí Ọba kọ̀ lati kópa nínú ọdún

Ara ọtọ ni ọdun ijẹṣu ilu Ilara mọkin tọdun yi gba yọ pẹlu bi awọn ọmọ ilu ti ṣe yabo aafin tuntun Ọba to ri pe ko foju han nibi ayẹyẹ naa.

Origun pataki ayẹyẹ naa ni ki Ọba Alara ilu Ilara Mokin yọju si awọn ọdọ ilu lasiko ajọdun naa.

Amọ Kabiyesi ni ohun ko lọwọ si ajọdun naa nitori poe iwa ara oko ni ki eeyan ma na ara wọn lẹgba tori pe wọn n ṣe ajọdun

Gẹgẹ bi awọn ọdọ naa ti ṣe sọ ninu fọnran fidio ti BBC Yoruba ya lasiko ti wọn yabo aafin Ọba ,wọn ni itabukubaẹni ni bi Alara ko ti ṣe yọju sawọn.

Nibi wọduwọdu to waye niwaju aafin Ọba tuntun,arakunrin Onifansanyin Ayodeji fi ẹhonu rẹ han si Alara pẹlu bi Ọba alade naa ko ṣe kopa ninu ajọdun ijẹṣu.

''Bi a se n se nkan wa leleyi,bi ẹnikan ba si ni ni oun ko ni ṣe bẹẹ,oju rẹ yoo ri ohun tnikan ko ri ri. Bawo ni awọn eeyan yoo ṣe nawo nara wa lati ilu Oyinbo ti Alara ko ni yọju si wọn?''

Ẹkunrẹrẹ fidio bi ọrọ ti ṣe di boolọ o ya mi re loju opo Facbook BBC

A ko ribi fidi ọrọ mulẹ boya Kabiyesi ti gba lati dara pọ mọ ọdun ijẹsu tọdun yi amọ nibi ti fọnran fidio naa pari si,inu awọn ọdọ ko dun si aikopa rẹ.

Akọroyin wa jabọ pe awọn ọdọ ba ferese ati awọn aga jẹ nibi aafin tuntun Kabiyesi Alara ilu IlaraMokin.

E foju lounjẹ pẹlu awọn aworan to jẹyọ lati ilu Ilaramọkin ti ajọdun ijẹṣu ti n waye.