World University Ranking: Ibùdó ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìṣègùn Fásitì Ibadan dé ipò kẹrin l'Àfíríkà

Ẹnu ọna abawọle ibudo isegun fasiti Ibadan Image copyright @BestiaresG

Atilẹyin ti ileewe Fasiti Ibadan ṣe fun ibudo ẹkọsẹ isegun ileewe naa, lati lee jẹ ki wọn sẹ iṣẹ wọn lọna ti o tọ ati eyi ti o yẹ lo mu ki ibudo ẹ́kọ̀sẹ́ isegun ọ̀hun se ipo kẹ́rin ni Afirika.

Ọjọgbọn Olubunmi Olapade Olaopa lo salaye bẹẹ fun BBC Yoruba lasiko to n sọrọ lori bi ọpọn ibudo ẹkọsẹ isegun fasiti Ibadan se sun si ipo kẹrin ni ilẹ Afirika.

Olaopa ni pẹlu atilẹhin awọn oluranwọ miran, bi awọn akẹkọjade ileẹkọ naa, lo wa lara idi ti ileewe naa ṣe goke agba nilẹ Afirika.

O ṣalaye pe, "awa ọsiṣẹ ile iwe yii naa n sapa wa, ta si ti gbe awọn igbimọ kan kalẹ lati wo bi a ṣe lee de ipo agba. Gbogbo imọran ti wọn gba wa ni a tẹle, eyii lo ran wa lọwọ lati lee de ipo ti a de yii"

Image copyright @UIbadan
Àkọlé àwòrán Abawọle Fasiti Ibadan

Ọjọgbọn Olapade-Olaopa sọ pe, igba akọkọ ni yii ti ileewe naa yoo de ipo kẹrin ni gbogbo Afirika. Bi o tilẹ jeẹ pe ileewe naa ni aṣaju ni gbogbo agegbe aṣalẹ Sahara.

Ninu ọrọ ọjọgbon naa, o ṣalaye pe "Lọdun to kọja, ipo kẹjọ ni awa nilẹ Afirika lẹyin Fasiti Makerere to wa ni Uganda, sugbọn lana ode yii ni a goke agba si ipo kẹrin nilẹ adulawọ. Ti a si n tẹlẹ Egypt ati South Africa."

Ọjọgbọn Olaopa tun ṣalaye pe, ileewe ẹkọṣẹ iṣegun naa gbe ipo kẹrin nigba, to si n tẹle Fasiti Stellenbosch to wa ni South Africa, Fasiti Cairo ati Fasiti Mansoura, to wa ni orilẹ-ede Egypt.

Lori ọna ti ileewe naa yoo gba lati ri pe eegun ibudo iṣegun yii ko jo ajorẹyin, ọjọgbọn naa ni "a ti sun ṣokoto wa, ti a si n wo gbogbo awọn ibi to ku diẹ kaato fun atunse to yẹ."

Olaopa wa seleri pe ibudo ẹkọsẹ isegun fasiti Ibadan yoo maa wa atilẹhin gbogbo awọn to ti n ran wọn lọwọ latẹyinwa ati awọn ohun tuntun miran, ki wọn le duro si ipo giga yii."