Ìtàn Mánigbàgbé: Lúwòó Gbàgídà ló bí Adékọ́lá Telú tó tẹ ìlú Ìwó dó

Ere Ọọni tilu Ile Ifẹ Image copyright Facebook/OMO Lamurudu Media

Ni aye atijọ, ọpọ ọkunrin ni ọkan wọn maa n rẹwẹsi, ti wọn kii si dunnu ti wọn ba gbọ pe wọn bi obinrin gẹgẹ bii ọmọ tuntun.

Igbagbọ wọn ni pe obinrin ko lee dabira lawujọ bii awọn ọkunrin, wọn ro pe ọkunrin nikan lo lee jẹ eeyan takuntakun, ti yoo si sọ orukọ wọn di manigbagbe lọjọ ọla.

Wọn ko si ranti pe ohun ti ọkunrin lee se, awọn obinrin gan lee se daradara ju ọkunrin lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi ọrọ se ri ree pẹlu akọni obinrin kan to n jẹ Lúwòó Gbàgídà,ẹni tii se akinkanju, olokiki, olowo, ọlọrọ ati aya ọba nigba aye rẹ, to si se gudugudu meje ati yayaya mẹfa, lati mase jẹ ki itan rẹ parẹ ninu itan Yoruba.

Gẹgẹ ba se kaa loju opo Wikipedia, akikanju obinrin yii, Lúwòó Gbàgídà, ni Ọọni kọkanlelogun tilu Ile Ifẹ, tii se orirun gbogbo ọmọ Yoruba, to si jọba lẹyin Ọọni Giesi, Ọọni Lumọbi si lo jọba lẹyin rẹ.

Awọn ohun pataki nipa Ọọni Luwooo Gbagida:

  • Ọmọ Ataataa lati Idile Owode ladugbo Okerewe, to si fẹ Oloye Ọbalọran ti Ilode lọkọ
  • Akoko saa onka ẹẹdẹgbẹfa ọdun, eyiun 1100 AD ni Luwoo Gbagida jẹ Ọọni tilu Ile Ifẹ, to si di olori awọn ẹlẹsin ati alakoso asa fun ilẹ Yoruba.
  • A gbọ pe o jẹ arẹwa obinrin, ti ori rẹ si maa n wu nipa ẹwa rẹ eyi to maa n da ọpọ ọkunrin lọrun
  • Luwooo Gbagida mọ riri imọtoto pupọ, to si mu imọtoto aarin ilu lọkunkundun to si mu ki ọpọ araalu, ko si bi wọn se kanka to, maa sisẹ asekara fun imọtoto ayika lai yọ awọn ọkunrin silẹ
  • Luwooo Gbagida lo n lo ọwọ agbara ati oju agan sawọn eeyan to ba lọ tikọ lati se ohunkohun to ba ni ki wọn se
  • O maa n gun awọn ọlẹ ọkunrin bi ẹsin ni, ti wọn ba fi sẹ si ofin rẹ, ti kii si fi oju aanu wo ẹnikẹni to ba n se imẹlẹ
  • Luwooo Gbagida kii se obinrin kan to jẹ ẹran rirọ rara, ti ko si mọ iyatọ laarin ẹru ati ọmọ ilu to ba n se ọlẹ, bakan naa ni yoo se se wọn
  • Nitori pe Luwooo Gbagida ko fẹran lati maa fi ẹsẹ rin, ti ko si si bata ni aye igba naa, lo mu ko da okuta alaranbara sori awọn ilẹ to n rin kọja ati gbagede to ti maa n naju
  • Ọọni Luwoo bi ọmọkunrin kan to pe orukọ rẹ ni Adekọla Telu, to si se iranwọ fun ọmọ naa lati tẹ ilu Iwo do, to si tun jẹ Oluwo akọkọ
  • Nitori ọwọ lile to fi se akoso ilu lasiko to wa lori itẹ, ni awọn ijoye Ile Ifẹ se pinnu pe obinrin ko ni jẹ Ọọni mọ laelae.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌja Arena Oshodi ni àwọn èèyàn ti ń r'aja

Ohun ti itan Ọọni Lúwòó Gbàgídà kọ wa:

O kọ wa pe gbogbo lọmọ, ko baa jẹ ọkunrin abi obinrin, ko si eyi ti ko lee jẹ olokiki

Itan yii tun kọ wa lati mase jẹ okuroro

A tun ri kọ ninu itan yii lati maa jẹ onimọtoto