Kogi Governorship: Melaye fárígá, óní òun ó ṣe olùdarí ìpolongo ìbò gómìnà ní Kogí

Sẹnetọ Dino Melaye Image copyright Instagram/dinomelaye

Sẹnetọ Dino Melaye ti kọ iyansipo rẹ gẹgẹ bi oludari ipolongo fun ibo gomina ninu ẹgbẹ PDP ni ipinlẹ Kogi.

Melaye lo kede ọrọ yii loju opo Twitter rẹ.

O ni "Mo fẹ sọ ni kedere pe, mo ti kọ ipo oludari ipolongo fun ibo gomina ninu ẹgbẹ PDP ni ipinlẹ Kogi. Ire ooo."

Saaju ni alukoro apapọ fun ẹgbẹ naa, Kola Olagbodiyan, ti kede Melaye gẹge bi oludari ipolongo ibo ọhun lọjọ ẹti ki o to di pe o kọ ipo naa.

Ni ọjọ kẹrin oṣu yii ni Musa Wada, fi idi Melaye janlẹ ninu idibo abẹle sipo gomina ninu ẹgbẹ ọhun.

Wada to jẹ aburo si gomina ana ni ipinlẹ ọhun, lo fi idi Melaye janlẹ ninu idibo abẹle naa, pẹlu ibo to le ni ẹẹdẹgbẹrin, nigba ti Melaye ni ibo aadọrin pere.

Meleye ni awọn eeyan kan ti n wo bi ẹni to lee rọwọ mu ninu idibo abẹle naa, sugbon to fidi rẹmi.