Buhari: Bí kìí bá ṣe ìpàdé ìgbìmọ̀ aláṣẹ tí à ń ṣe, ìpayà kò bá bá mi kí ìgbẹ́jọ́ tó wáyé

Aarẹ Muhammadu Buhari Image copyright @BashirAhmaad

Yoruba ni adiẹ a mọọ laagun, amọ iyẹ ara rẹ ni kii jẹ ka mọ, bẹẹ lọrọ ri fun aarẹ Muhammadu Buhari lori abajade igbẹjọ ibo aarẹ.

Aarẹ Buhari, lasiko to n gbalejo awọn gomina to jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu APC to wa ki nile ijọba nilu Abuja, jẹwọ pe lootọ ni ojora mu oun ko to di pe igbimọ to n gbọ awuyewuye ibo aarẹ gbe idajọ wọn kalẹ lori ẹjọ naa.

Buhari ni ọpẹlọpẹ pe oun n dari ipade igbimọ alasẹ ijọba to n waye lọwọ lasiko ti awọn ọmọ igbimọ olugbẹjọ n gbe idajọ wọn kalẹ ni, iporuru ọkan ko ba ba oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igba akọkọ ti aarẹ Buhari yoo si se ipade pẹlu awọn ọmọ igbimọ alasẹ rẹ to sẹsẹ yan fun saa keji ni ọjọ naa, ti igbẹjọ n waye bakan naa lori boya o fidi rẹmi abi o yege ibo aarẹ to kọja.

"Akoko taa lo nibi ipade igbimọ alasẹ naa tun jẹ iye akoko ti igbimọ olugbẹjọ lo lati gbe idajọ wọn kalẹ, mo dupẹ pe eyi waye, bibẹẹkọ idaamu ọkan ko ba ba mi, mo kan n tiraka lati gbajumọ awọn iwe to wa niwaju mi ni."

Ijẹwọ Buhari yii si lo yatọ gedegede si ohun ti alaga ẹgbẹ oselu APC, Adams Oshiomole n sọ pe ẹgbẹ oselu APC ati aarẹ Buhari ko tiẹ mikan rara lori ibi ti igi igbẹjọ naa yoo wo si.