Ogun Police: Ìgbájú lásán ni ọkọ fún ìyàwó tó sì gba ibẹ̀ kú

Aworan ọkọ to n na iyawo Image copyright Others

Ibinu ko mọ pe olowo oun ko lẹsẹ nlẹ, bẹẹ si ni ibinu isẹju kan maa n sọ ile alayọ di kikan.

Kingsley Madukwe tii se ẹni ogoji ọdun ti n kawọn pọnyin rojọ ni olu ileesẹ ọlọpa to wa nilu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun lori ẹsun pe o lu iyawo rẹ, Glory Madukwe pa tori ibinu.

Atẹjade kan ti alukoro fun ileesẹ ọlọpa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi fisita lori isẹlẹ naa salaye pe, ọkunrin naa, lo gba iyawo rẹ, ti oun naa jẹ ẹni ogoji ọdun, ni igbati lasan, ti onitọun si gba ibẹ dagbere faye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade naa ni ohun suusu ni esu su mọ tọkọtaya yii lọwọ, ti wọn ti bi ọmọ mẹjọ fun ara wọn, nigba ti ọmọ osu kan ti iyawo gbe dani n sọkun, amọ ti obinrin naa kọ lati fun ni ọmu, ko lee dakẹ ẹkun.

Image copyright Others

Niwọn igba ti ibinu ko si mọ pe olowo oun ko lẹsẹ nilẹ, bi obinrin naa se dide lai dahun si ọrọ ọkọ rẹ pe ko fun ọmọ to n sunkun lọyan, ti obinrin naa si fi ọkọ gun lagidi, to n wọ inu ile lọ, ni ibinu ba gba ọkan ọkunrin yii, to si ba iyawo rẹ wa igbati.

Gẹgẹ bi Oyeyẹmi ti wi, igbati olooyi ti ọkunrin ọlọkada naa fun aya rẹ lo mu ki obinrin naa, to ti n saroye tẹlẹ pe o rẹ oun, mu idi lọ silẹ to si gba ibẹ jẹ ipe Ọlọrun.

Oyeyẹmi ni aago mọkanla aabọ alẹ ni isẹlẹ naa sẹlẹ, ti Baalẹ adugbo naa si fi isẹlẹ yii to ileesẹ ọlọpa leti, eyi to mu ki ọwọ tete tẹ ọkunrin naa.