FUOYE: Fayemi ní ìṣẹ̀lẹ̀ bí àwọn ìrètí ọ̀la náà ṣe kú ba òun nínú jẹ́

Gómìnà Fayemi ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn sí ẹbí akẹ́kọ̀ọ́ fásitì FUOYE méjì t'ọ́lọ́pàá pa nílùú Ọyẹ́ Ekiti Image copyright Ekiti state government

Gomina Kayọde Fayẹmi ti ipinlẹ Ekiti ti ranṣẹ ibanikẹdun lọ ki awọn ẹbi akẹkọọ meji ti ọlọpaa yinbọn pa.

Awọn akẹkọọ naa jẹ alaisi lasiko rogbodiyan to waye laarin awọn ọlọpaa ati akẹkọ fasiti FUOYE, pẹlu awọn olugbe ilu Ọyẹ Ekiti.

Awọn akẹkọọ meji ọhun, Joseph Okunofua ati Kehinde Dada jade laye lẹyin ti iroyin sọ pe, ọta ibọn ba wọn lasiko iwọde awọn akẹkọọ ati awọn olugbe ilu naa ni ọjọ Iṣẹgun ati Ọjọru.

Họnọrebu Biọdun Oyebanji, to jẹ akọwe ijọba ipinlẹ Ekiti pẹlu Họnọrebu Biọdun Ọmọlẹyẹ, to jẹ olori awọn oṣiṣẹ to n ba gomina ipinlẹ Ekiti ṣiṣẹ, lo ṣiwaju ikọ olubanikẹdun naa.

Ikọ olubanikẹdun ọhun lọ si ilu Ido-Ekiti nibiti wọn ti ṣabẹwo si arabinrin Esther Okunofua, to jẹ iya Joseph akẹkọọ ipele kẹta ẹka imọ Biology ni fasiti FUOYE, ki o to jade laye.

Image copyright Ekiti state government

Bakan naa ni wọn tun de ilu Uṣi Ekiti, nibi ti wọn ti ki alagba Adedayọ Dada to jẹ baba fun Kẹhinde.

Họnọrebu Oyebanji ṣalaye pe, iṣẹlẹ naa jẹ eyi ti o ba gomina Fayẹmi ninu jẹ pupọ ati pe, kii ṣe idunu rẹ ki awọn obi mejeeji yii padanu ọkan lara awọn ireti ọla wọn.