YouTube ń polówó àwọn iléeṣẹ ńlá pẹlú àwọn fídíò ayédèrú ìwòsàn ààrùn jẹjẹrẹ

Igo ogun kan pẹlu ami idanimọ YouTube

Oju opo Youtube a maa ṣe koriya fun awọn ipolowo ọja ayederu oogun apa koko arun jẹjẹrẹ eyi ti ipolowo rẹ n waye loriṣiriṣi ede.

Oju opo naa a si maa gbe awọn ipolowo ọja fun awọn eroja ati fasiti ti o n ṣi araye lọna lori rẹ, gẹgẹ bii iwadii BBC ṣe fidi rẹ mulẹ.

Ayẹwo lori oju opo Youtube fihan gbangba fun BBC pe, o le ni ọgọrin awọn fidio aṣini lọna nipa eto ilera to wa, ninu oniruuru ede mẹwa ta tọpasẹ wọn.

Paapaa julọ nipa iwosan aisan jẹjẹrẹ ni ọpọ awọn fidio naa da le lori, mẹwa ninu wọn lo jẹ pe ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu awọn eeyan lo ti wo o, pẹlu oniruru ipolowo ọja ninu rẹ.

Lara awọn iwosan ti ko ni ifidimulẹ wọnyi ni wọn ti tọka sawọn eroja kan bii Turmeric abi baking soda ati bẹẹbẹẹ lọ.

Awọn miran tilẹ tun n rọ awọn eeyan lati mu ọmu rakunmi tabi omi gbigbona, ko si eyikeyi ninu awọn iwosan wọnyii ti wọn ti fi idi rẹ mulẹ nipa iwadii.

Image copyright YouTube

Lara awọn ipolowo ọja to n farahan ninu awọn fidio iwosan ayederu wọnyii, la ti ri awọn ipolowo ọja awọn eroja to lamilaaka bii Samsung, Heinz ati Clinique.

Pẹlu ilana ipolowo ọja Youtube, o fihan pe atohun atawọn to ṣe fidio awọn ogun ayederu wọnyii ni wọn n pa owo wọle sapo ara wọn nipa ṣiṣi araalu lọna.

Wọn ti oju opo ede gẹẹsi pa ṣugbọn wọn ṣi awọn ede miran silẹ

Ni oṣu Kinni, YouTube kede pe oun yoo mu adinku ba iye awọn fidio to n ṣafihan awọn ohun to n ṣi araalu lọna, paapaa awọn fidio to n ṣe igbelarugẹ awọn amulumala iṣẹ iyanu to n wo awọn aisan kan san.

Amọṣa, ileeṣẹ YouTube ni ede oyinbo nikan ni eyii yoo ti kọkọ farahan ati pe, ko kan awọn ede miran lẹyin ede Gẹẹsi.

Iwadi ati ayẹwo ti BBC ṣe kan awọn ede bii Gẹẹsi, Potoki, Ruṣia, Larubawa, Paṣia, Hindi, jamani, Ukureni, Faranse pẹlu ede Aguda.

Image copyright YouTube

Pipa owo wọle nipa ṣiṣi araalu lọna

Ọpọ awọn oluwadii ẹka BBC Monitorin ati BBC News Brasil lo tẹwọ gba awọn ipolowo ọja kan ṣaaju awọn fidio ayederu iwosan wọnyii.

Yatọ si awọn ipolowo ọja Samsung, Heinz ati Clinique, BBC tun ri awọn ipolowo ọja ikanni ayelujara kan to da lori irinajo, iwe kikọ, fiimu agbelewo Hollywood ati awọn fasiti ilẹ Gẹẹsi.

Gbogbo wọn ni wọn n farahan ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu awọn iroyin aṣinilọna wọnyii.

Samsung ni ko si ohun to kan ipolowo ọja ti wọn pẹlu ohun to wa ninu awọn fidio ayederu iwosan aisan jẹjẹrẹ naa, orin yii kan naa ni Kraft Heinz pẹlu n kọ lẹnu.

Grammarly ni oun ti kan si YouTube pe ko yọ ipolowo ọja oun kuro lori rẹ ni kete ti ọrọ naa ti lu si awọn lọwọ. Amọṣa, ileeṣẹ Clinique ni tirẹ ko fesi si ibeere ti wọn fi ranṣẹ sii lori ọrọ yii.

Bawo ni YouTube ṣe n yan ipolowo ọja ti iwọ oluworan fidio wọn n ri?

Ipolowo ọja lori oju opo YouTube le wa fun awọn eeyan kan lawujọ. Tim Schoyer to n mojuto bi fidio ṣe n jade loju opo YouTube ṣalaye pe, ilana yiyan fidio ti yoo lọ tabi ti araalu yoo ri, wọnu ara wọn diẹ.