Fídíò rèé tó ń sọ bí ọdún ìjẹṣu ṣe di ìjàgboro ní ìlú Ilaramọkin
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ilaramokin: Ọba yarí pé àṣá àìlajú ni kí ará ìlú máa na ara wọn lẹ́gba

Se ni ọrọ di boo lọ, ko yago fun mi nilu Ilaramọkin ni ọjọ Ẹti lasiko ti ọdun ijẹsu di ija igboro.

Asiko ọdun ijẹsu yii ni awọn ara ilu, ọba ati awọn ijoye rẹ yoo maa jo yika ilu, ti awọn ọdọ yoo si maa na ara wọn ni atori.

Sugbọn ọrọ bẹyin yọ lọdun yii lasiko ọdun ijẹsu nigba ti Alara ti ilu Ilaramọkin, Ọba Abiọdun Aderẹmi Adefẹyinti faake kọri pe oun ko ni kopa ninu ọdun naa nitori asa nina ara ẹni lẹgba.

Alara ni ountako asa naa nitori pe ko ba igba mu mọ sugbọn awọn ọdọ ti ọps wọn wa lati ẹyin odi ati oke okun lo yari mọ ọba lọwọ, ti ọrọ naa si di isu ata yanyan.

Bi isẹlẹ naa se waye ree ninu fidio yii.