Yollywood: Toyin Abraham ní òun fẹ́ fòpin sí ìbànilórúkọjẹ́ tí Lizzy ń ṣe

Lizzy Anjorin ati Toyin Abraham

Oju opo Instagram n gbona lọwọlọwọ bayii nitori ede aiyede to n waye laarin awọn gbajumọ osere obinrin meji, Toyin Abraham ati Lizzy Anjọrin.

Bẹẹ ba gbagbe eefin ija laarin awọn mejeeji lo ru sita nigba ti awọn ololufẹ Toyin fi ẹsun kan Lizzy pe ko se agbelarugẹ Toyin lasiko to bimọ gẹgẹ bo se maa n se fun awọn osere tiata yoku.

Lẹ́yin eyi ni Lizzy gbe ọpọ ọrọ to nii se pẹlu Toyin si oju opo instagram rẹ eyi to fi n fi ẹsun kan Toyin pe, oun lo ni oju opo ayelujara kan to n gbe iroyin jade, to si ta ba oun, ti oun si ni ẹri to daju lọwọ nipa rẹ.

Idi si ree ti Lizzy se n tahun si Toyin pe oun n lọ sẹba ile rẹ, ti wahala yoo si bẹrẹ, bẹẹ ni awọn ololufẹ Toyin n fun lesi pada, tawọn ololufẹ Lizzy naa si n da wọn lohun, ti ọrọ wa di ranto.

Lizzy ni "Onirọ, ọmọ ale... se iwọ nikan lo ni awọn ololufẹ to maa n fa wahala lẹsẹ ni? Ki lo de ti awọn ololufẹ rẹ ko se maa huwa bayii ni ọdun kan si meji sẹyin? Nibo ni wọn wa nigba ti wọn n wọ ẹ pẹlu ololufẹ rẹ, Ẹgbẹgbẹ Asiri ti tu."

Sugbọn ni bayii, aawọ naa ti fẹju si, ti Toyin si ni lọjọ Aje ni agbẹjọro oun yoo kan si Lizzy Anjọrin lati wọ lọ sile ẹjọ lori ẹsun ibanilorukọ jẹ to n se si oun loju opo ikansira ẹni rẹ.

Nigba to n fesi lori awọn ọrọ ti Lizzy n sọ nipa rẹ yii loju opo Instagram tiẹ naa, Toyin Abraham kede pe, asiko ti to ti oun fẹ fopin si gbogbo ẹsun ibalorukọ jẹ yii, ti ileeẹjọ yoo si jọ gba awọn mejeeji.

"O ti de etigbọ mi pe awọn ọjẹwẹwẹ kan to n dibọn bii osere tiata lo n wọ orukọ mi sinu ere itage ti wọn n se nigba kuugba ti wọn ba wa lori ayelujara. Emi naa ti se iru eyi sẹyin, ti n ko si wọ orukọ ẹnikẹni sinu rẹ. Osere tiata kan lobinrin lo darukọ mi lati ba mi lorukọ jẹ, ohun to si fẹ gba ko ye mi, amọ emi ko ni wọ ara mi sinu ẹrọfọ pẹlu rẹ."

Toyin ni gbogbo ẹri ti onitọhun ni pe oun lo ni oju opo iroyin kan ko ju pe, oun fesi si ọrọ ti ẹnikan sọ nibẹ, ohun ko si mọ ohun to kan oun, to si n rọ osere naa, to han pe Lizzy ni, lati dẹkun didi ẹbi ẹlomiran si ori oun.

Toyin wa kadi ọrọ rẹ nilẹ pe, Lizzy yoo gburo agbẹro oun lọjọ Aje nitori oun fẹ fi ofin kasẹ awọn iwa idunkooko mọ ni to n se si oun lori ayelujara nilẹ.