Orò Festival: 5.30 ìrọ̀lẹ́ si 5.30 ìdájí ní àwọn olórò yóò fi máa yíde ìlú

Awon to n ṣe ọdun Oro Image copyright @Oyomatters

Wayi o, igbakeji alaga fun ẹgbẹ agbaagba nilu Isẹyin, Alhaji Bọlaji Kareem, ti kede pe ija ti dopin, ogun si ti tan lori aawọ ọrọ sise nilu Isẹyin.

Kareem, ẹni to soju Asẹyin nibi ipade ipẹtu saawọ kan ti ẹgbẹ agbaagba naa seto salaye pe, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni, awọn igbimọ Imaamu ati Alfa nilu Isẹyin, to fi mọ ẹgbẹ ẹlẹsin ọmọlẹyin Kristi, CAN atawọn abọrẹ oro mẹrẹẹrin nilu naa, lo peju sibi ipade ọhun.

Nibi ipade naa lo ni wọn ti fẹnu ọrọ jona lati jẹ ki ogun o sinmi, ti awọn oloro yoo si maa se oro wọn lati aago marun aabọ irọlẹ si marun idaji, ti wọn ko si ni yaju si ẹnikẹni.

Bakan naa, etutu oro ti gbera nilu Isẹyin lọjs Aje oni pẹlu bibẹ aja sidi Ogun to wa loju ọja.

Image copyright @OtunbaAlaoAkala

Àwọn tó ń da ẹ̀sìn pọ̀ mọ́ àṣà ló fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀ lórí ọdún orò - Asẹ́yìn

Asẹyin ti ilu Isẹyin ti ṣalaye pe, awọn eeyan kan ti ko da iyatọ mọ laarin ẹsin ati aṣa lo fẹ da wahala silẹ pẹlu ọdun oro ilu Isẹyin.

Kabiyesi Abdulganiyu Adekunle Salau ni lootọ ni ọdun oro yoo waye ni ilu Isẹyin fun ọjọ mẹtadinlogun ṣugbọn ọjọ mẹta pere ni wọn yoo fi gbe oro lasiko ọdun naa.

O ni awọn perete kan ti oye ko ye laarin awọn ẹlẹsin musulumi ni ilu isẹyin, lo n lewaju ifẹhonu han naa.

Ninu ọrọ to ba BBC news Yoruba sọ, Asẹyin ni ijiroro ti waye lori rẹ, wọn si ti yanju ọrọ ọhun.

Ẹ gbọ Asẹyin siwaju si ninu fọnran ohun yii:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOrò Festival: Asẹ́yìn ní ìwọ̀nba péréte làwọn Mùsùlùmí tó ń tako ọdún orò ní ìlú Ìsẹ́yìn

Ẹ̀yin olórò ní Isẹyin kò leè dí wa lọ́wọ́ láti yan fanda fọ́jọ́ 17 - Ẹgbẹ́ Mùṣùlùmí yarí

Image copyright @Oyomatters

Igbimọ to ga julọ fun ẹsin Musulumi, NSCIA, ẹka ti ilu isẹyin ni ipinlẹ Ọyọ, ti kilọ fun awọn to n ṣe ọdun oro ni ilu naa, lori ipinnu wọn pe ko ni si irinkerindo awọn eeyan fun ọjọ mẹtadinlogun.

NSCIA ni awọn to n ṣe ọdun oro yii lo ṣe ikọlu si awọn eeyan kan lọdun to kọja, ti wọn si pa wọn ni ipakupa. Eyi ti ẹgbẹ naa fi lọ ajọ ọlọpaa ati gomina ipinlẹ Ọyọ lọjọ kejila, oṣu kẹwa ọdun naa.

Ajọ naa sọ siwaju pe, ọwọ agbofinrro tẹ lara awọn to ṣe ikọlu naa, sugbọn ti wọn fiwọn silẹ lai foju ba ile ẹjọ.

Alaga igbimọ NSCIA, Raji Coker sọ pe, awọn to n ṣọdun oro naa kan n pariwo ẹnu lasan ni, lọna lati tan awọn agbofinro ati gomina ipinlẹ Ọyọ jẹ, pẹlu bi wọn ti sọ pe, igbimọ ọhun ko gbawọn laaye lati ṣe ọdun oro wọn.

Image copyright @abati1990

Agbẹnusọ fun NSCIA ni Isẹyin, Mallam Maruf Mustapha ṣalaye fun awọn akọroyin pe, awuyewuye to waye lọsẹ to kọja lori bi ẹgbẹ Ebedi Frontliners ṣe sọ fun gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde pe, orin ija ẹsin ni ẹgbẹ NSCIA kọ, ko ri bẹẹ rara.

Mustapha ni ẹgbe NSCIA ko gbe igbẹsẹ kankan lati da ọdun oro duro, ati pe ẹgbẹ naa ko ṣe ikọlu kankan si awọn to n ṣe ọdun oro.

Image copyright @Oyomatters

Mustapha wa sọ fun awọn agbofinro lati ji giri nitori awuyewuye to lee waye, gẹgẹ bi awọn oloro naa ṣe fẹ dena ẹtọ awọn ẹlẹsin miran ni ilu ọhun lati rin bo se wu wọn fun ọjọ mẹtandinlogun, nitori ọdun oro ti wọn n ṣe.

Ṣaaju ni Oludari ikede fun ẹgbẹ Ebedi Frontliners, Sẹgun Fasasi ti fi ẹsun kan ajọ NSCIA, pe ẹgbẹ naa lọ si ile ẹjo lati da ọdun oro naa duro, to si fi kun pe, eyi jẹ ọna lati da rogbodiyan silẹ ni ilu Isẹyin.