Majek Fashek: Ṣé lóòtọ́ ni Òdú olórin Raggae, Majek Fashek jáde láyé?

Majek Fashek Image copyright Majek Fashek

Iroyin kan ni ọjọ aiku pe lo gbalẹ kan pe gbajugbaja olorin Raggae ọmọ Naijiria nni, Majek Fashek ti dagbere faye.

Ohun ti iroyin naa, eleyii to ti farahan lori ọpọlọpọ awọn oju opo aiyelujara titi kan Wikipedia ṣalaye pe, Majek Fashek mi eemi ikẹyin rẹ ni ọjọ Aiku ni ilu London, ni orilẹede Gẹẹsi.

Amọṣa, ohun ti alamojuto ẹgbẹ oṣere rẹ, Uzoma Omenka sọ ninu fidio kan, eyi to fi sita loju opo instagram Majek Fashek ni pe, ko si nnkan to ṣe Majek o.

O ni ko ku, ṣugbọn ara rẹ ko le.

Fidio naa eyi to fi sita ni nnkan bii agogo mejila oru ọjọ Aje, Uzoma Omenka ni ko yẹ ki ẹnikẹni maa gbadura iku fun agba onkọrin naa.

nigba ti BBC Yoruba kan sii, O ni ohun to nile ni owo iranwọ fun itọju rẹ ati pe ọpọ awọn eeyan lo ti n pe lọtun losi lati igba ti iroyin naa ti jade.

"Majek ko ku o, ojojo diẹ̀ lo kan n ṣe ogun rẹ"

Ti a ba n sọ ninu awọn onkọrin ọmọ orilẹede Naijiria ti gbogbo agbaye mọ bi ẹnii mọ owo, ti orin rẹ si ti gbe ogo ba orilẹede Naijiria ni ọpọlọpọ igba, Majek Fashek jẹ ọkan pataki ninu wọn.

Ọdun 1962 ni wọn bi Majek Fashek ni ilu Benin, ni ipinlẹ Edo.

Ni aipẹ yii ni iroyin kan kọkọ jade pe arun jẹjẹrẹ mu Majek Fashek ti wọn si n beere iranlọwọ fun un,

Iroyin iku rẹ kọkọ ti tan jade ni ọjọ diẹ sẹyin ki alamojuto ẹgbẹ akọrin rẹ, Uzoma Omenka to gbe fidio kan sita pe irọ ni ṣugbọn o fi idi rẹ mulẹ nigba naa pe lootọ ni aisan da agba akọrin naa dubu

Amọṣa iroyin naa ṣebi ẹni pe ko dawọ duro.

Lara awọn manigbagbe orin ti Majek Fashek gbe jade ni Send down the rain eyi to fun un ni inagijẹ The rainmaker. Awo orin Prisoner of Conscience and I&I Experience(1989),So long too long (1991)

Orukọ abisọ rẹ gangan ni Majẹkodunmi Fasheke.

Ile iwosan Queen Elizabeth Hospital, Woolwich ni o ti n gba iwosan ni ilu London.lẹ.