Fake Pastor: Ọlọ́pàá mú aṣaájú ẹgbẹ́ òkùnkùn 'Ẹiyẹ Confraternity'

Ileeṣẹ ọlọpaa ni oniruuru ẹsun lo wa lọrun afunrasi ti wọn mu naa eleyii ti iwadii yoo sọ bi ẹjọ rẹ yoo ṣe ri. Image copyright @PoliceNG

Ọwọ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti tẹ arakunrin kan ti wọn ni o jẹ ijakumọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ Confraternity, ni agbegbe Bariga ni ilu Eko.

Inagijẹ ti ọpọ eeyan mọ arakunrin naa si ni ‘Pasitọ’ lai ni ile ijọsin kankan, ṣugbọn orukọ abisọ rẹ a maa jẹ Emmanuel Ọlatunde.

Iroyin ti a gbọ sọ pe, ọwọ tẹ arakunrin ọhun lori ẹsun ọkan o jọkan iwa ipaniyan ati idigunjale lagbegbe ijọba ibilẹ Bariga.

Gẹgẹ bi atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Bala Elkana fi sita, Ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn ni Ọlatunde, o si ti fi igba kan ri lọ ṣe saa diẹ lọgba ẹwọn.

O ni ọwọ rẹ lawọn ọlọpaa ba ninu iku Ọgbẹni Ahmed Karonwi, ti oun pẹlu jẹ ilumọọka ọmọ ẹgbẹ okunkun 'Aiye Confraternity'

Ikọlu awọn ẹgbẹ okunkun ti n di tọrọfọnkale nipinlẹ Eko, eleyii ti ileeṣẹ ọẹọpaa ni ilakaka n lọ lati wa ọwọ rẹ bọlẹ.